Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 21:22 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 Jesu wí fún un pé, “Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kín ni èyí jẹ́ sí ọ? Ìwọ máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

22 Jesu dá a lóhùn pé, “Bí mo bá fẹ́ kí ó wà títí n óo fi dé, èwo ni ó kàn ọ́? Ìwọ sá máa tẹ̀lé mi ní tìrẹ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

22 Jesu wi fun u pe, Bi emi ba fẹ ki o duro titi emi o fi de, kili eyini si ọ? Ìwọ mã tọ̀ mi lẹhin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 21:22
20 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.


Nítorí bí mọ̀nàmọ́ná ti ń tàn láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́.


Bí ó ti jókòó ní orí òkè Olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ̀ ọ́ wá ní ìkọ̀kọ̀, wọ́n wí pé, “Sọ fún wa nígbà wo ni èyí yóò ṣẹlẹ̀? Kí ni yóò jẹ́ ààmì ìpadà wá rẹ, àti ti òpin ayé?”


Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ wà ní ìmúrasílẹ̀, nítorí ní wákàtí àìròtẹ́lẹ̀ ni dídé Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́.


“Ṣùgbọ́n nígbà ti Ọmọ Ènìyàn yóò wá nínú ògo rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn angẹli rẹ̀ nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo ní ọ̀run.


Ṣùgbọ́n Jesu wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn, sì jẹ́ kí àwọn òkú kí ó máa sin òkú ara wọn.”


Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín àwọn mìíràn wa nínú àwọn tó dúró níhìn-ín yìí, tí kì yóò tọ́ ikú wò, títí yóò fi rí ìjọba Ọlọ́run tí yóò fi dé pẹ̀lú agbára.”


Jesu wí èyí, ó fi ń ṣe àpẹẹrẹ irú ikú tí yóò fi yin Ọlọ́run lógo. Lẹ́yìn ìgbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”


Nígbà tí Peteru rí i, ó wí fún Jesu pé, “Olúwa, Eléyìí ha ńkọ́?”


Nítorí nígbàkúgbà tí ẹ bá ń jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ǹ mu nínú ago yìí, ni ẹ tún sọ nípa ikú Olúwa. Ẹ máa ṣe eléyìí títí yóò fi padà dé.


Nítorí náà, kí ẹ má ṣe ṣe ìdájọ́ ohunkóhun, kí Olúwa tó padà dé, ẹni tí yóò mú ohunkóhun tí ó fi ara sin wá sí ìmọ́lẹ̀, tí yóò sì fi ìmọ̀ ọkàn ènìyàn hàn, nígbà náà ni olúkúlùkù yóò sì ní ìyìn tirẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.


Kí ni ìrètí wa, ayọ̀ wa, tàbí adé wa nínú èyí tí a ó ṣògo níwájú Jesu Olúwa nígbà tí òun bá dé? Ṣé ẹ̀yin kọ́ ni?


Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di ìpadà wá Olúwa. Kíyèsi i, àgbẹ̀ a máa retí èso iyebíye ti ilẹ̀, a sì mú sùúrù dè é, títí di ìgbà àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò.


Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù; ẹ fi ọkàn yín balẹ̀: nítorí ìpadà wá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀.


Kíyèsi i, o ń bọ̀ nínú àwọsánmọ̀; gbogbo ojú ni yóò sì rí i, àti àwọn tí ó gún un ní ọ̀kọ̀ pẹ̀lú; àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni yóò sì máa pohùnréré ẹkún nítorí rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni! Àmín.


Ṣùgbọ́n èyí tí ẹ̀yin ní, ẹ di mú ṣinṣin títí èmi ó fi dé.


Ẹni tí ó jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí wí pé, “Nítòótọ́ èmi ń bọ̀ kánkán.” Àmín, Máa bọ̀, Jesu Olúwa!


“Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán! Ìbùkún ni fún ẹni tí ń pa ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́!”


Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán: di èyí ti ìwọ ní mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gba adé rẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan