Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 20:9 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 (Nítorí tí wọn kò sá à tí mọ ìwé mímọ́ pé, Jesu ní láti jíǹde kúrò nínú òkú.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 (Nítorí ohun tí Ìwé Mímọ́ wí kò tíì yé wọn pé dandan ni kí ó jí dìde ninu òkú.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Nitoripe nwọn kò sá ti imọ̀ iwe-mimọ́ pe, on kò le ṣaima jinde kuro ninu okú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 20:9
22 Iomraidhean Croise  

nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú, tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.


Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì, ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi; ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú.


Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé. Olúwa Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù, kúrò ní ojú gbogbo wọn; Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé. Olúwa ni ó ti sọ ọ́.


Ṣùgbọ́n àwọn òkú yín yóò wà láààyè ara wọn yóò dìde. Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀, dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀. Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀, ayé yóò bí àwọn òkú rẹ̀ lọ́mọ.


“Èmi yóò rà wọ́n padà kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú. Èmi yóò rà wọ́n padà lọ́wọ́ ikú Ikú, àjàkálẹ̀-ààrùn rẹ dà? Isà òkú, ìparun rẹ dà? “Èmi kò ní ṣàánú mọ́.


Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àìmọ̀kan yín ni ó fa irú ìbéèrè báyìí. Nítorí ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́ àti agbára Ọlọ́run.


Kò ha yẹ kí Kristi ó jìyà nǹkan wọ̀nyí kí ó sì wọ inú ògo rẹ̀ lọ.”


Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, ó sì ṣú wọn lójú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ̀ ọ́n: ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti béèrè ìdí ọ̀rọ̀ náà.


Nítorí náà nígbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé, ó ti sọ èyí fún wọn; wọ́n sì gba ìwé Mímọ́, àti ọ̀rọ̀ tí Jesu ti sọ gbọ́.


Ó ń túmọ̀, ó sì ń fihàn pé, Kristi kò lè ṣàìmá jìyà, kí o sì jíǹde kúrò nínú òkú; àti pé, “Jesu yìí ẹni tí èmi ń wàásù fún yin, òun ni Kristi náà.”


Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, gbà á kúrò nínú ìrora ikú: nítorí tí kò ṣe é ṣe fún ikú láti dìímú.


Àti pé a sìnkú rẹ̀, àti pé ó jíǹde ní ọjọ́ kẹta gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ tí wí;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan