Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 20:25 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

25 Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù wí fún un pé, “Àwa ti rí Olúwa!” Ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Bí kò ṣe pé mo bá rí àpá ìṣó ni ọwọ́ rẹ̀ kí èmi sì fi ìka mi sí àpá ìṣó náà, kí èmi sì fi ọwọ́ mi sí ìhà rẹ̀, èmi kì yóò gbàgbọ́!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

25 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù sọ fún un pé, “Àwa ti rí Oluwa!” Ṣugbọn ó sọ fún wọn pé, “Bí n kò bá rí àpá ìṣó ní ọwọ́ rẹ̀, kí n fi ìka mi kan ibi tí àpá ìṣó wọ̀n-ọn-nì wà, kí n fi ọwọ́ mi kan ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, n kò ní gbàgbọ́!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

25 Nitorina awọn ọmọ-ẹhin iyokù wi fun u pe, Awa ti ri Oluwa. Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Bikoṣepe mo ba ri àpá iṣo li ọwọ́ rẹ̀ ki emi ki o si fi ika mi si àpá iṣó na, ki emi ki o si fi ọwọ́ mi si ìha rẹ̀, emi kì yio gbagbó.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 20:25
25 Iomraidhean Croise  

Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn, èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi.


Àwọn ajá yí mi ká; ìjọ àwọn ènìyàn ibi ti ká mi mọ́, Wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́sẹ̀


Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ síwájú; nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́


Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀ pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là, kò sí lè gba ara rẹ̀. Ìwọ ọba àwọn Israẹli? Sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú nísinsin yìí, àwa yóò sì gbà ọ́ gbọ́.


Àti àwọn, nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé Jesu wa láààyè, àti pé, òun ti rí i, wọn kò gbàgbọ́.


Nígbà tí wọ́n sì mọ ẹni tí i ṣe, wọ́n sì lọ ròyìn fún àwọn ìyókù, síbẹ̀, àwọn ìyókù kò gbà wọ́n gbọ́.


Lẹ́yìn náà, Jesu fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn mọ́kànlá níbi tí wọ́n ti ń jẹun papọ̀; Ó sì bá wọn wí fún àìgbàgbọ́ àti ọkàn líle wọn, nítorí wọn kò gba ẹ̀rí àwọn tí ó ti rí i lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀ gbọ́.


Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́:


Ohun àkọ́kọ́ tí Anderu ṣe ni láti wá Simoni arákùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí Messia” (ẹni tí ṣe Kristi).


Nígbà náà ni ó wí fún Tomasi pé, “Mú ìka rẹ wá níhìn-ín yìí, kí o sì wo ọwọ́ mi; sì mú ọwọ́ rẹ wá níhìn-ín, kí o sì fi sí ìhà mi: kí ìwọ má ṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́ mọ́, ṣùgbọ́n jẹ́ onígbàgbọ́.”


Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà tí Jesu fẹ́ràn wí fún Peteru pé, “Olúwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Olúwa ni, bẹ́ẹ̀ ni ó di àmùrè ẹ̀wù rẹ̀ mọ́ra, nítorí tí ó wà ní ìhòhò, ó sì gbé ara rẹ̀ sọ sínú Òkun.


Nígbà náà ni wọ́n wí fún wọn pé, “Iṣẹ́ ààmì kín ní ìwọ ń ṣe, tí àwa lè rí, kí a sì gbà ọ́ gbọ́? Iṣẹ́ kín ní ìwọ ṣe?


Ẹ kíyèsára, ará, kí ọkàn búburú ti àìgbàgbọ́ má ṣe wà nínú ẹnikẹ́ni yín, ní lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.


Àwọn wo ni ó búra fún pé wọn kì yóò wọ inú ìsinmi òun, bí kò ṣe fún àwọn tí ó ṣe àìgbọ́ràn?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan