Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 2:20 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

20 Nígbà náà ní àwọn Júù wí pé, “Ọdún mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ni a fi kọ́ tẹmpili yìí, ìwọ ó ha sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

20 Àwọn Juu wí fún un pé, “Aadọta ọdún ó dín mẹrin ni ó gbà wá láti kọ́ Tẹmpili yìí, ìwọ yóo wá kọ́ ọ ní ọjọ́ mẹta?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

20 Nigbana li awọn Ju wipe, Ọdún mẹrindiladọta li a fi kọ́ tẹmpili yi, iwọ o ha si gbé e ró ni ijọ mẹta?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 2:20
6 Iomraidhean Croise  

Ní ọdún kọkànlá ní oṣù Bulu, oṣù kẹjọ, a sì parí ilé náà jálẹ̀ jálẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìpín rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó yẹ. Ó sì lo ọdún méje ní kíkọ́ ilé náà.


“Nígbà náà ni Ṣeṣbassari náà wá, ó sí fi ìpìlẹ̀ ilé Ọlọ́run tí ó wá ní Jerusalẹmu lélẹ̀, láti ìgbà náà àní títí di ìsinsin yìí ni o ti n bẹ ní kíkọ́ ṣùgbọ́n, kò sí tí ì parí tán.”


Bí Jesu ti ń kúrò ni tẹmpili, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n fẹ́ fi ẹwà tẹmpili náà hàn án.


Bí àwọn kan sì ti ń sọ̀rọ̀ nípa tẹmpili, bí a ti fi òkúta dáradára àti ẹ̀bùn ṣe é ní ọ̀ṣọ́, fun Ọlọ́run, Jesu wí pé


Èyí sì ni ẹ̀rí Johanu, nígbà tí àwọn Júù rán àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi láti Jerusalẹmu wá láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ẹni tí òun ń ṣe.


Àti pé a sìnkú rẹ̀, àti pé ó jíǹde ní ọjọ́ kẹta gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ tí wí;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan