Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 2:16 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Ó sì wí fún àwọn tí ń ta àdàbà pé, “Ẹ gbé nǹkan wọ̀nyí kúrò níhìn-ín; ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Ó sọ fún àwọn tí ń ta ẹyẹlé pé, “Ẹ gbé gbogbo nǹkan wọnyi kúrò níhìn-ín, ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ìtajà!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 O si wi fun awọn ti ntà àdaba pe, Ẹ gbe nkan wọnyi kuro nihin; ẹ máṣe sọ ile Baba mi di ile ọjà tità.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 2:16
17 Iomraidhean Croise  

Ṣé ilé yìí, tí a fi orúkọ mi pè ti di ihò àwọn ọlọ́ṣà lọ́dọ̀ yín ni? Èmi ti ń wò ó! ni Olúwa wí.


Jesu sì wọ inú tẹmpili, Ó sì lé àwọn ti ń tà àti àwọn tí ń rà níbẹ̀ jáde. Ó yí tábìlì àwọn onípàṣípàrọ̀ owó dànù, àti tábìlì àwọn tí ó ń ta ẹyẹlé.


Ó wí fún wọn pé, “A sá à ti kọ ọ́ pé, ‘Ilé àdúrà ni a ó máa pe ilé mi,’ ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùdó àwọn ọlọ́ṣà.”


“Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀n-ọn-nì tí ó ránṣẹ́ lọ pè kò kà á si. Wọ́n ń bá iṣẹ́ wọn lọ, ọ̀kan sí ọ̀nà oko rẹ̀, òmíràn sí ibi òwò rẹ̀.”


Gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ wọn, ó wí pé, “Ṣé a kò ti kọ ọ́ pé: ‘Ilé àdúrà ni a o máa pe ilé mi, ní gbogbo orílẹ̀-èdè?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ọlọ́ṣà.”


Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri, ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi?”


Baba mi, ẹni tí ó fi wọ́n fún mi pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò sì ṣí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Baba mi.


Ó sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe pàṣán, ó sì lé gbogbo wọn jáde kúrò nínú tẹmpili, àti àgùntàn àti màlúù; ó sì da owó àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nù, ó si ti tábìlì wọn ṣubú.


Jesu wí fún un pé, “Má ṣe fi ọwọ́ kàn mí; nítorí tí èmi kò tí ì gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi: ṣùgbọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin mi, sì wí fún wọn pé, ‘Èmi ń gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi, àti Baba yín: àti sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi, àti Ọlọ́run yín.’ ”


Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsin yìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.”


Jesu sì dáhùn pé, “Èmi kò ní ẹ̀mí èṣù, ṣùgbọ́n èmi ń bu ọlá fún Baba mi, ẹ̀yin kò sì bu ọlá fún mi.


àti ọ̀rọ̀ àríyànjiyàn àwọn ènìyàn ọlọ́kàn èérí ti kò sí òtítọ́ nínú wọn, tiwọn ṣe bí ọ̀nà sí èrè ni ìwà-bí-Ọlọ́run; yẹra lọ́dọ̀ irú àwọn wọ̀nyí.


Nínú ìwà wọ̀bìà wọn, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ òdì wọ̀nyí yóò máa rẹ́ ẹ yín jẹ nípa ìtàn asán. Ìdájọ́ ẹni tí kò falẹ̀ láti ìgbà yìí wá àti ìparun wọn tí kò sí tòògbé.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan