Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 2:11 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Èyí jẹ́ àkọ́ṣe iṣẹ́ ààmì, tí Jesu ṣe ní Kana ti Galili. Ó sì fi ògo rẹ̀ hàn; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Èyí ni ìbẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe ní Kana ti Galili. Èyí gbé ògo rẹ̀ yọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Akọṣe iṣẹ àmi yi ni Jesu ṣe ni Kana ti Galili, o si fi ogo rẹ̀ hàn; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbà a gbọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 2:11
43 Iomraidhean Croise  

Obìnrin náà sì wí fún Elijah pé, “Nísinsin yìí mo mọ̀ pé ènìyàn Ọlọ́run ni ìwọ ń ṣe, àti pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa ní ẹnu rẹ.”


Olùbùkún ni orúkọ rẹ̀ tí ó lógo títí láé; kí gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀. Àmín àti Àmín.


Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.


Nígbà ti àwọn ọmọ Israẹli rí iṣẹ́ ìyanu ńlá ti Olúwa ṣe fún wọn lára àwọn ará Ejibiti, àwọn ènìyàn bẹ̀rù Olúwa, wọ́n sì gba Olúwa àti Mose ìránṣẹ́ rẹ gbọ́.


Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gba ààmì méjèèjì wọ̀nyí gbọ́, tí wọn kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ, bu omi díẹ̀ láti inú odò Naili kí o si dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀, omi tí ìwọ bù láti inú odò yìí yóò sì di ẹ̀jẹ̀.”


Lọ jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ayọ̀, kí o sì mu ọtí wáìnì rẹ pẹ̀lú inú dídùn dé ọkàn, nítorí pé ìsinsin yìí ni Ọlọ́run ṣíjú àánú wo ohun tí o ṣe.


Ògo Olúwa yóò sì di mí mọ̀ gbogbo ènìyàn lápapọ̀ ni yóò sì rí i. Nítorí ẹnu Olúwa ni ó ti sọ ọ́.”


Bí ẹ̀yin kò bá ni gbọ́, bí ẹ̀yin kò bá ní fi í sí àyà láti fi ọ̀wọ̀ fún orúkọ mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí; èmi yóò sì ran ègún sí orí yín, èmi yóò sì fi ìbùkún yín ré. Nítòótọ́ mó ti fi ré ná, nítorí pé, ẹ̀yin kò fi sí ọkàn yín láti bu ọlá fún mi.


Ọ̀rọ̀ náà sì di ara, òun sì ń bá wa gbé. Àwa sì ti rí ògo rẹ̀, àní ògo ọmọ rẹ kan ṣoṣo, tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.


Nítorí pé nípasẹ̀ Mose ni a ti fi òfin fún ni ṣùgbọ́n òun; oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ láti ipasẹ̀ Jesu Kristi wá.


Ní ọjọ́ kejì Jesu ń fẹ́ jáde lọ sí Galili, ó sì rí Filipi, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”


Jesu sì wí fún un pé, “Ìwọ gbàgbọ́ nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́. Ìwọ ó rí ohun tí ó pọ̀jù ìwọ̀nyí lọ.”


Àwọn ènìyàn púpọ̀ sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Johanu kò ṣe iṣẹ́ ààmì kan: Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni ohun gbogbo tí Johanu sọ nípa ti ọkùnrin yìí.”


Èmi sì yọ̀ nítorí yín, tí èmi kò sí níbẹ̀. Kí ẹ le gbàgbọ́; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.”


Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi pe ìgbìmọ̀ jọ. Wọ́n sì wí pé, “Kín ni yóò jẹ àṣeyọrí wa? Nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ààmì.


Nítorí èyí ni ìjọ ènìyàn sì ṣe lọ pàdé rẹ̀, nítorí tí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ ààmì yìí.


Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ààmì tó báyìí lójú wọn, wọn kò gbà á gbọ́.


Nǹkan wọ̀nyí ni Isaiah wí, nítorí ó ti rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀.


Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì béèrè ní orúkọ mi, òun náà ni èmi ó ṣe, kí a lè yin Baba lógo nínú Ọmọ.


Nítorí tí Baba tìkára rẹ̀ fẹ́ràn yín, nítorí tí ẹ̀yin ti fẹ́ràn mi, ẹ sì ti gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni èmi ti jáde wá.


Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé, ìwọ mọ̀ ohun gbogbo, ìwọ kò ní kí a bi ọ́ léèrè: nípa èyí ni àwa gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ ti jáde wá.”


Ní ọjọ́ kẹta, wọn ń ṣe ìgbéyàwó kan ní Kana ti Galili. Ìyá Jesu sì wà níbẹ̀,


Nígbà tí ó sì wà ní Jerusalẹmu, ní àjọ ìrékọjá, lákokò àjọ náà, ọ̀pọ̀ ènìyàn gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ nígbà tí wọ́n rí iṣẹ́ ààmì tí ó ṣe.


Òun náà ní ó tọ Jesu wá ní òru, ó sì wí fún un pé, Rabbi, àwa mọ̀ pé olùkọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ìwọ ń ṣe: nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè ṣe iṣẹ́ ààmì wọ̀nyí tí ìwọ ń ṣe, bí kò ṣe pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.


Ó fi Judea sílẹ̀, ó sì tún lọ sí Galili.


Bẹ́ẹ̀ ni Jesu tún wá sí Kana ti Galili, níbi tí ó gbé sọ omi di wáìnì. Ọkùnrin ọlọ́lá kan sì wá, ẹni tí ara ọmọ rẹ̀ kò dá ní Kapernaumu.


Èyí ni iṣẹ́ ààmì kejì tí Jesu ṣe nígbà tí ó ti Judea jáde wá sí Galili.


Kí gbogbo ènìyàn lè máa fi ọlá fún ọmọ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń fi ọlá fún Baba. Ẹnikẹ́ni tí kò bá fi ọlá fún ọmọ, kò fi ọlá fún Baba tí ó ran an.


Nítorí náà nígbà tí àwọn ọkùnrin náà rí iṣẹ́ ààmì tí Jesu ṣe, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà tí ń bọ̀ wá sí ayé.”


Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, nítorí tí wọ́n rí iṣẹ́ ààmì rẹ̀ tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn.


Jesu dá wọn lóhùn ó sì wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín. Ẹ̀yin ń wá mi, kì í ṣe nítorí tí ẹ̀yin rí iṣẹ́ ààmì, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀yin jẹ àjẹyó ìṣù àkàrà.


Nígbà náà ni wọ́n wí fún wọn pé, “Iṣẹ́ ààmì kín ní ìwọ ń ṣe, tí àwa lè rí, kí a sì gbà ọ́ gbọ́? Iṣẹ́ kín ní ìwọ ṣe?


Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn sì gbà á gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Nígbà tí Kristi náà bá dé, yóò ha ṣe iṣẹ́ ààmì jù wọ̀nyí, tí ọkùnrin yìí ti ṣe lọ?”


Nítorí náà àwọn kan nínú àwọn Farisi wí pé, “Ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, nítorí tí kò pa ọjọ́ ìsinmi mọ́.” Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Ọkùnrin tí í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò ha ti ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ ààmì wọ̀nyí?” Ìyapa sì wà láàrín wọn.


Ṣùgbọ́n gbogbo wa ń wo ògo Olúwa láìsí ìbòjú bí ẹni pé nínú àwòjìji, a sì ń pa wa dà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, àní bí láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí í ṣe Ẹ̀mí.


Nítorí ìpọ́njú díẹ̀ yìí ń pèsè ògo tí ó ní ìwọ̀n ayérayé tí ó pọ̀ rékọjá sílẹ̀ fún wa.


Nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ó wí pé, “Kí ìmọ́lẹ̀ ó tan láti inú òkùnkùn jáde,” òun ní ó ti ń tan mọ́lẹ̀ lọ́kàn wa, láti fún wa ní ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọ́run ní ojú Jesu Kristi.


Ẹ sì sọ pé, “Olúwa Ọlọ́run wa ti fi ògo rẹ̀ hàn wá, àti títóbi rẹ̀ a sì ti gbóhùn rẹ̀ láti àárín iná wá. A ti rí i lónìí pé, ènìyàn sì lè wà láààyè lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá bá a sọ̀rọ̀.


Nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ̀wé rẹ̀ sí yín, àní sí ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́; kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ẹ̀yin ní ìyè àìnípẹ̀kun, àní fún ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan