Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 19:5 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Nítorí náà Jesu jáde wá, ti òun ti adé ẹ̀gún àti aṣọ elése àlùkò. Pilatu sì wí fún wọn pé, Ẹ wò ọkùnrin náà!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Nígbà náà ni Jesu jáde pẹlu adé ẹ̀gún ati ẹ̀wù àlàárì. Pilatu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkunrin náà nìyí.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Nitorina Jesu jade wá, ti on ti ade ẹgún ati aṣọ elesè àluko. Pilatu si wi fun wọn pe, Ẹ wò ọkunrin na!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 19:5
8 Iomraidhean Croise  

Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Sioni, lọ sí orí òkè gíga. Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jerusalẹmu, gbé ohùn rẹ sókè pẹ̀lú ariwo, gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù; sọ fún àwọn ìlú u Juda, “Ọlọ́run rẹ nìyìí!”


Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí Olúwa wí nìyìí ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu ẹni tí ó mọ ọ́, Ìwọ Israẹli: “Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè; Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe.


Nítorí náà, Olúwa fúnra ara rẹ̀ ni yóò fún ọ ní ààmì kan. Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli.


“Kò ha jẹ́ nǹkan kan sí i yín? Gbogbo ẹ̀yin tí ń rékọjá, Ǹjẹ́ ẹnìkan ń jìyà bí èmi ti ń jìyà tí a fi fún mi, ti Olúwa mú wá fún mi ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀.


Wọ́n sì hun adé ẹ̀gún. Wọ́n sì fi dé e lórí. Wọ́n sì fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ọba. Wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n fi í ṣe ẹlẹ́yà pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!”


Ní ọjọ́ kejì, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!


Àwọn ọmọ-ogun sì hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí, wọ́n sì fi aṣọ ìgúnwà elése àlùkò wọ̀ ọ́.


Kí a máa wo Jesu Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan