Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 19:3 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Wọ́n sì wí pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!” Wọ́n sì fi ọwọ́ wọn gbá a ní ojú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 wọ́n wá ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń kí i pé, “Kabiyesi! Ọba àwọn Juu!” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbá a létí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Nwọn si wipe, Kabiyesi, Ọba awọn Ju! nwọn si fi ọwọ́ wọn gbá a loju.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 19:3
7 Iomraidhean Croise  

Nísinsin yìí, Judasi wá tààrà sọ́dọ̀ Jesu, ó wí pé, “Àlàáfíà, Rabbi” ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu.


Wọ́n sì hun adé ẹ̀gún. Wọ́n sì fi dé e lórí. Wọ́n sì fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ọba. Wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n fi í ṣe ẹlẹ́yà pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!”


Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i kí ì, wí pé Kábíyèsí, ọba àwọn Júù


Angẹli náà sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Àlàáfíà fun ọ, ìwọ ẹni tí a kọjú sí ṣe ní oore, Olúwa ń bẹ pẹ̀lú rẹ.”


Bí ó sì ti wí èyí tan, ọ̀kan nínú àwọn aláṣẹ tí ó dúró tì í fi ọwọ́ rẹ̀ lu Jesu, pé, “alábojútó àlùfáà ni ìwọ ń dá lóhùn bẹ́ẹ̀?”


Nítorí náà, Pilatu tún wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́ lọ, ó sì pe Jesu, ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ha ni a pè ni ọba àwọn Júù bí?”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan