Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 19:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nítorí náà ni Pilatu mú Jesu, ó sì nà án.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Nígbà náà ni Pilatu mú Jesu, ó ní kí wọ́n nà án.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 NITORINA ni Pilatu mu Jesu, o si nà á.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 19:1
16 Iomraidhean Croise  

Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi: wọ́n sì la aporo wọn gígùn.


Mo ṣí ẹ̀yìn mi sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń nà mí, àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irùngbọ̀n mi; Èmi kò fi ojú mi pamọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́yà àti ìyọṣùtì sí.


Ṣùgbọ́n a sá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedéédéé wa a pa á lára nítorí àìṣòdodo wa; ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lórí i rẹ̀, àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi mú wa láradá.


Wọn yóò sì fà á lé àwọn kèfèrí lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà àti láti nàa án, àti láti kàn mi mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta, yóò jí dìde.”


Nítorí náà èmi yóò rán àwọn wòlíì àti àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin tí ó kún fún ẹ̀mí mímọ́, àti àwọn akọ̀wé sí yín. Ẹ̀yin yóò pa àwọn kan nínú wọn nípa kíkàn wọ́n mọ́ àgbélébùú. Ẹ̀yin yóò fi pàṣán na àwọn ẹlòmíràn nínú Sinagọgu yín, tí ẹ̀yin yóò sì ṣe inúnibíni sí wọn láti ìlú dé ìlú.


Wọn ó sì nà án, wọn ó sì pa á: ní ọjọ́ kẹta yóò sì jíǹde.”


Ǹjẹ́ èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀ lọ.”


Wọ́n túbọ̀ tẹramọ́ igbe ńlá, wọ́n ń fẹ́ kí a kàn án mọ́ àgbélébùú, ohùn tiwọn àti ti àwọn olórí àlùfáà borí tirẹ̀.


Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín ẹyọ kan lọ́wọ́ àwọn Júù.


Àwọn ẹlòmíràn sì rí ìjìyà ẹ̀sín, àti nínà, àti ju bẹ́ẹ̀ lọ, ti ìdè àti ti túbú:


Ẹni tí òun tìkára rẹ̀ fi ara rẹ̀ ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi àgbélébùú, pé kí àwa lè di òkú sí ẹ̀ṣẹ̀, ki a sì di ààyè sí òdodo: nípa ìjìyà ẹni tí ó mú yín láradá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan