Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 18:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Jesu dáhùn pé, “Mo ti wí fún yín pé, èmi nìyí: ǹjẹ́ bí èmi ni ẹ bá ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọ̀nyí máa lọ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Jesu wí fún wọn pé, “Mo sọ fun yín pé èmi gan-an nìyí. Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni ẹ̀ ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọnyi máa lọ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Jesu dahùn pe, Mo ti wi fun nyin pe, emi niyi: njẹ bi emi li ẹ ba nwá, ẹ jẹ ki awọn wọnyi mã lọ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 18:8
13 Iomraidhean Croise  

Gbogbo wa bí àgùntàn, ti ṣìnà lọ, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀; Olúwa sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀ gbogbo àìṣedéédéé wa.


Ṣùgbọ́n gbogbo wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a tì ẹnu àwọn wòlíì sọ, tí a kọ sínú Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ.” Nígbà yìí gan an ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sálọ.


Èmi sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun; wọn kì yóò sì ṣègbé láéláé, kò sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ mi.


Ǹjẹ́ kí àjọ ìrékọjá tó dé, nígbà tí Jesu mọ̀ pé, wákàtí rẹ̀ dé tan, tí òun ó ti ayé yìí kúrò lọ sọ́dọ̀ Baba, fífẹ́ tí ó fẹ́ àwọn tirẹ̀ tí ó wà ní ayé, ó fẹ́ wọn títí dé òpin.


Simoni Peteru wí fún un pé, “Olúwa, níbo ni ìwọ ń lọ?” Jesu dá a lóhùn pé, “Níbi tí èmi ń lọ, ìwọ kì yóò lè tẹ̀lé mí nísinsin yìí; ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ̀ mí lẹ́yìn ní ìkẹyìn.”


Kíyèsi i, wákàtí ń bọ̀, àní ó dé tan nísinsin yìí, tí a ó fọ́n yín ká kiri, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀; ẹ ó sì fi èmi nìkan sílẹ̀: ṣùgbọ́n kì yóò sì ṣe èmi nìkan, nítorí tí Baba ń bẹ pẹ̀lú mi.


Nítorí náà ó tún bi wọ́n léèrè, wí pé, “Ta ni ẹ ń wá?” Wọ́n sì wí pé, “Jesu ti Nasareti.”


Kí ọ̀rọ̀ nì kí ó lè ṣẹ, èyí tó wí pé, Àwọn tí ìwọ fi fún mi, èmi kò sọ ọ̀kan nù nínú wọn.”


Kò sí ìdánwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó mọ níwọ̀n fún ènìyàn, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlọ́run, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ́n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ̀yin ba à lè faradà á.


Òun sì wí fún mi pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ: nítorí pé a sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” Nítorí náà tayọ̀tayọ̀ ni èmi ó kúkú máa fi ṣògo nínú àìlera mi, kí agbára Kristi lè máa gbé inú mi.


Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un.


Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé e; nítorí tí òun ń ṣe ìtọ́jú yín.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan