Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 16:5 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi; kò sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó bi mí lérè pé, ‘Níbo ni ìwọ ń lọ?’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Ṣugbọn nisinsinyii mò ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. Ẹnìkankan ninu yín kò wí pé, ‘Níbo ni ò ń lọ?’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Ṣugbọn nisisiyi emi nlọ sọdọ ẹniti o rán mi; kò si si ẹnikan ninu nyin ti o bi mi lẽre pe, Nibo ni iwọ nlọ?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 16:5
15 Iomraidhean Croise  

Tí Jesu sì ti mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, àti pé lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni òun ti wá, òun sì ń lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run;


Simoni Peteru wí fún un pé, “Olúwa, níbo ni ìwọ ń lọ?” Jesu dá a lóhùn pé, “Níbi tí èmi ń lọ, ìwọ kì yóò lè tẹ̀lé mí nísinsin yìí; ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ̀ mí lẹ́yìn ní ìkẹyìn.”


“Ẹ̀yin sá ti gbọ́ bí mo ti wí fún yín pé, ‘Èmi ń lọ, èmi ó sì tọ̀ yín wá.’ Ìbá ṣe pé ẹ̀yin fẹ́ràn mi, ẹ̀yin ìbá yọ̀ nítorí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba; nítorí Baba mi tóbi jù mí lọ.


Ní ti òdodo, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ̀yin kò sì mọ̀ mí;


“Nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ si, ẹ ó sì rí mi, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.”


Nítorí náà díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bá ara wọn sọ pé, “Kín ni èyí tí o wí fún wa yìí, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yin kì yóò rí mi: àti, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba?”


Mo ti ọ̀dọ̀ Baba jáde wá, mo sì wá sí ayé: àti nísinsin yìí mo fi ayé sílẹ̀, mo sì lọ sọ́dọ̀ Baba.”


“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, nǹkan wọ̀nyí ni mo sì ń sọ ní ayé, kí wọn kí ó lè ní ayọ̀ mi ní kíkún nínú àwọn tìkára wọn.


Èmi ti yìn ọ́ lógo ní ayé: èmi ti parí iṣẹ́ tí ìwọ fi fún mi láti ṣe.


Ǹjẹ́, bí ẹ̀yin bá sì rí i tí ọmọ ènìyàn ń gòkè lọ sí ibi tí ó gbé ti wà rí ńkọ́?


Nítorí náà Jesu wí fún wọn pé, “Níwọ́n ìgbà díẹ̀ ni èmi yóò wà pẹ̀lú yín, èmi yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó rán mi.


Ọmọ tí í ṣe ìtànṣán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkára rẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró: Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọláńlá ní òkè.


Kí a máa wo Jesu Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan