Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 16:26 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

26 Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin ó béèrè ní orúkọ mi: èmi kò sì wí fún yín pé, èmi ó béèrè lọ́wọ́ Baba fún yín:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

26 Ní ọjọ́ náà, ẹ óo bèèrè nǹkan ní orúkọ mi, n kò ní wí fun yín pé èmi yóo ba yín bẹ Baba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

26 Li ọjọ na ẹnyin o bère li orukọ mi: emi kò si wi fun nyin pe, emi o bère lọwọ Baba fun nyin:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 16:26
9 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà èmi yóò wá béèrè lọ́wọ́ Baba. Òun yóò sì fún yín ní olùtùnú mìíràn. Olùtùnú náà yóò máa bá yín gbé títí láé


Ní ọjọ́ náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi wà nínú Baba mi, àti ẹ̀yin nínú mi, àti èmi nínú yín.


Jesu sá à ti mọ̀ pé, wọ́n ń fẹ́ láti bi òun léèrè, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ń bi ara yín léèrè ní ti èyí tí mo wí pé, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ si, ẹ̀yin ó sì rí mi?


Àti ní ọjọ́ náà ẹ̀yin kì ó bi mí lérè ohunkóhun. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, òhun ó fi fún yín.


Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé, ìwọ mọ̀ ohun gbogbo, ìwọ kò ní kí a bi ọ́ léèrè: nípa èyí ni àwa gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ ti jáde wá.”


Èmi sì ya ara mi sí mímọ́ nítorí wọn, kí a lè sọ àwọn tìkára wọn pẹ̀lú di mímọ́ nínú òtítọ́.


“Baba, èmi fẹ́ kí àwọn tí ìwọ fi fún mi, kí ó wà lọ́dọ̀ mi, níbi tí èmi gbé wà; kí wọn lè máa wo ògo mi, tí ìwọ ti fi fún mi: nítorí ìwọ sá à fẹ́ràn mi síwájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.


Èmi ń gbàdúrà fún wọn: èmi kò gbàdúrà fún aráyé, ṣùgbọ́n fún àwọn tí ìwọ ti fi fún mi; nítorí pé tìrẹ ni wọ́n í ṣe.


Ta ni ẹni náà tí yóò dá wa lẹ́bi? Kò sí. Kristi Jesu tí ó kú, kí a sá à kúkú wí pé tí a ti jí dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí ó sì wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, tó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan