Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 16:21 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Nígbà tí obìnrin bá ń rọbí, a ní ìbìnújẹ́, nítorí tí wákàtí rẹ̀ dé: ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá ti bí ọmọ náà tán, òun kì í sì í rántí ìrora náà mọ́, fún ayọ̀ nítorí a bí ènìyàn sí ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

21 Nígbà tí aboyún bá ń rọbí, ó gbọdọ̀ jẹ ìrora, nítorí àkókò ìkúnlẹ̀ rẹ̀ tó. Ṣugbọn nígbà tí ó bà bímọ tán, kò ní ranti gbogbo ìrora rẹ̀ mọ́, nítorí ayọ̀ pé ó bí ọmọ kan sinu ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

21 Nigbati obinrin bá nrọbi, a ni ibinujẹ, nitoriti wakati rẹ̀ de: ṣugbọn nigbati o ba ti bí ọmọ na tan, on kì si iranti irora na mọ́, fun ayọ̀ nitori a bí enia si aiye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 16:21
18 Iomraidhean Croise  

Ọlọ́run wí fún obìnrin náà pé: “Èmi yóò fi kún ìrora rẹ ní àkókò ìbímọ; ni ìrora ni ìwọ yóò máa bí ọmọ. Ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóò máa fà sí, òun ni yóò sì máa ṣe àkóso rẹ.”


Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ, ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti sàn kọjá lọ.


Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé, àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀. Ẹ yin Olúwa.


Ẹ̀rù yóò gbá wọn mú, ìrora àti ìpayínkeke yóò dìwọ́n mú, wọn yóò kérora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí. Ẹnìkínní yóò wo ẹnìkejì rẹ̀ pẹ̀lú ìpayà ojú wọn á sì gbinájẹ.


Pẹ̀lú èyí, ìrora mu mi lára gírígírí, ìrora gbá mi mú, gẹ́gẹ́ bí i ti obìnrin tí ń rọbí, Mo ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nítorí ohun tí mo gbọ́, ọkàn mi pòruurù nípa ohun tí mo rí.


“Kí ó tó lọ sí ìrọbí, ó ti bímọ; kí ó tó di pé ìrora dé bá a, ó ti bí ọmọkùnrin.


Máa yí síhìn-ín sọ́hùn-ún nínú ìrora, ìwọ obìnrin Sioni, bí ẹni tí ń rọbí, nítorí nísinsin yìí ìwọ yóò jáde lọ kúrò ní ìlú, ìwọ yóò sì máa gbé inú igbó. Ìwọ yóò lọ sí Babeli; níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì ti rí ìgbàlà. Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ.


Kí ni ìwọ ha ń kígbe sókè sí nísinsin yìí? Ǹjẹ́ ìwọ kò ní ọba bí? Àwọn ìgbìmọ̀ rẹ ṣègbé bí? Nítorí ìrora ti dì ọ́ mú bí obìnrin tí ń rọbí.


Nítorí a ti kọ ọ́ pé, “Máa yọ̀, ìwọ obìnrin àgàn tí kò bímọ, bú sí ayọ̀ kí o sì kígbe sókè, ìwọ tí kò rọbí rí; nítorí àwọn ọmọ obìnrin náà tí a kọ̀sílẹ̀ yóò pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ.”


Ní àkókò gan an tí àwọn ènìyàn yóò máa wí pé, “Àlàáfíà àti ààbò,” nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìrọbí obìnrin tí ó lóyún, wọn kò sí ni rí ibi ààbò láti sá sí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan