Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 15:25 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

25 Ṣùgbọ́n èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a kọ nínú òfin wọn kí ó lè ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi ní àìnídìí.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

25 Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a kọ ninu Òfin wọn lè ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi láìnídìí.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

25 Ṣugbọn eyi ṣe ki ọ̀rọ ti a kọ ninu ofin wọn ki o le ṣẹ pe, Nwọn korira mi li ainidi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 15:25
16 Iomraidhean Croise  

Wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìríra yí mi káàkiri; wọ́n bá mi jà láìnídìí


Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ lórí ì mi; bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe àwọn tí ó kórìíra mi ní àìnídìí máa ṣẹ́jú sí mi.


Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí wọ́n ju irun orí mi; lọ púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí, àwọn tí ń wá láti pa mí run A fi ipá mú mi láti san ohun tí èmi kò jí.


Bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mi, tí mo ja ọ̀tá mi lólè láìnídìí:


Ẹ máa ṣe ìwòsàn fún àwọn aláìsàn, ẹ si jí àwọn òkú dìde, ẹ sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, kí ẹ sì máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fi fún ni.


Ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín, nígbà tí èmí ti wà pẹ̀lú yín pé: A ní láti mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ nínú òfin Mose, àti nínú ìwé àwọn wòlíì, àti nínú Saamu, nípasẹ̀ mi.”


Jesu dá wọn lóhùn pé, “A kò ha tí kọ ọ́ nínú òfin yín pé, ‘Mo ti wí pé, Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́’?


“Kì í ṣe ti gbogbo yín ni mo ń sọ: èmi mọ àwọn tí mo yàn: ṣùgbọ́n kí Ìwé mímọ́ bá à lè ṣẹ, ‘ẹni tí ń bá mi jẹun pọ̀ sì gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sí mi.’


Nǹkan wọ̀nyí ṣe, kí ìwé mímọ́ ba à lè ṣẹ, tí ó wí pé, “A kì yóò fọ́ egungun rẹ̀.”


Àwa sì mọ̀ pé ohunkóhun tí òfin bá wí, ó ń wí fún àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin: kí gbogbo ẹnu bá à lè dákẹ́ àti kí a lè mú gbogbo aráyé wá sábẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run.


Àwọn ẹni tí a ń dá láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kristi Jesu:


Tàbí ẹ̀ṣẹ̀ ni mo dá bí èmi ti ń rẹ ara mí sílẹ̀ kí a lè gbé yín ga, nítorí tí mo wàásù ìhìnrere Ọlọ́run fún un yín lọ́fẹ̀ẹ́.


Èmi kò ya oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sí apá kan: nítorí pé bí a bá le ti ipasẹ̀ òfin jèrè òdodo, a jẹ́ pé Kristi kú lásán.”


Bẹ́ẹ̀ ni àwa kò sì jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, àwa ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru kí a má ba à di àjàgà sí ẹnikẹ́ni nínú yín lọ́rùn.


Ó sì wí fún mi pé, “Ó parí. Èmi ni Alfa àti Omega, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin. Èmi ó sì fi omi fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ láti inú orísun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.


Ẹ̀mí àti ìyàwó wí pé, “Máa bọ!” Àti ẹni tí ó ń gbọ́ kí ó wí pé, “Máa bọ̀!” Àti ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ kí ó wá, àti ẹni tí o bá sì fẹ́, kí ó gba omi ìyè náà lọ́fẹ̀ẹ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan