Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 15:22 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 Ìbá ṣe pé èmi kò ti wá kí n sì ti bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n di aláìríwí fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

22 Bí n kò bá wá láti bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, wọn kò ní àwáwí fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

22 Ibaṣepe emi kò ti wá ki n si ti ba wọn sọrọ, nwọn kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi nwọn di alairiwi fun ẹ̀ṣẹ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 15:22
17 Iomraidhean Croise  

Bí wọn fetísílẹ̀ tàbí wọn kò fetísílẹ̀—nítorí pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n—wọn yóò mọ̀ pé wòlíì kan wà láàrín wọn.


Olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà yóò dé ní ọjọ́ tí kò retí rẹ̀, àti ní wákàtí tí kò dábàá, yóò sì jẹ ẹ́ ní yà gidigidi, yóò sì yan ipò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.


Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò sì gba ọ̀rọ̀ mi, ó ní ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀; ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ, òun náà ni yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.


Ẹni tí ó bá kórìíra mi, ó kórìíra Baba mi pẹ̀lú.


Ìbá ṣe pé èmi kò ti ṣe iṣẹ́ wọ̀n-ọn-nì láàrín wọn tí ẹlòmíràn kò ṣe rí, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n sì rí, wọ́n sì kórìíra èmi àti Baba mi.


ní ti ẹ̀ṣẹ̀, nítorí tí wọn kò gbà mí gbọ́;


Jesu dá a lóhùn pé, “Ìwọ kì bá tí ní agbára kan lórí mi, bí kò ṣe pé a fi í fún ọ láti òkè wá: nítorí náà ẹni tí ó fi mí lé ọ lọ́wọ́ ni ó ní ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀jù.”


Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé ẹ̀yin fọ́jú, ẹ̀yin kì bá tí lẹ́sẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa ríran,’ nítorí náà ẹ̀ṣẹ̀ yín wà síbẹ̀.


Pẹ̀lúpẹ̀lú ìgbà àìmọ̀ yìí ni Ọlọ́run tí fojú fò dá; ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti ronúpìwàdà;


Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀: bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.


Nítorí náà, aláìríwí ni ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́ tí ń dá ni lẹ́jọ́: nítorí nínú ohun tí ìwọ ń ṣe ìdájọ́ ẹlòmíràn, ìwọ ń dá ara rẹ lẹ́bi; nítorí ìwọ tí ń dájọ́ ń ṣe ohun kan náà nínú èyí tí ìwọ ń dá ni lẹ́jọ́.


Nítorí náà ẹni tí ó bá mọ rere í ṣe tí kò sì ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un.


Ẹ máa gbé gẹ́gẹ́ bí ẹni òmìnira, ṣùgbọ́n ẹ ma ṣe lo òmìnira yín láti bo ibi mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n kí ẹ gbé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan