Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 15:21 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n yóò ṣe sí yín, nítorí orúkọ mi, nítorí tí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

21 Wọn yóo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi si yín nítorí tèmi, nítorí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

21 Ṣugbọn gbogbo nkan wọnyi ni nwọn o ṣe si nyin, nitori orukọ mi, nitoriti nwọn kò mọ̀ ẹniti o rán mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 15:21
35 Iomraidhean Croise  

Nítorí rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn, ìtìjú sì bo ojú mi.


Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, Ẹ̀yin tí ẹ ń wárìrì nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀: “Àwọn arákùnrin yín tí wọ́n kórìíra yín, tí wọ́n ta yín nù nítorí orúkọ mi, wí pé, ‘Jẹ́ kí a yin Olúwa lógo, kí a le rí ayọ̀ yín!’ Ṣùgbọ́n àwọn ni ojú yóò tì.


Nítorí orúkọ mi, a ó mú yín lọ síwájú àwọn baálẹ̀ àti àwọn ọba, bí ẹlẹ́rìí sí wọn àti àwọn aláìkọlà.


Gbogbo ènìyàn yóò sì kórìíra yín nítorí mi, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni tí ó bá dúró ṣinṣin dé òpin ni a ó gbàlà.


Ẹni tí ó bá wa ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nú nítorí tèmi ni yóò rí i.


“Nígbà náà ni a ó sì dá a yín lóró. A ó pa yín, a ó sì kórìíra yín ni gbogbo orílẹ̀-èdè, nítorí pé ẹ̀yin jẹ́ tèmi.


“Alábùkún fún ni ẹ̀yin nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi àbùkù kàn yín tí wọn bá ṣe inúnibíni sí yín, tiwọn fi ètè èké sọ̀rọ̀ búburú gbogbo sí yín nítorí mi.


Àwọn ènìyàn yóò kórìíra yín nítorí tí ẹ jẹ́ tèmi. Ṣùgbọ́n ẹni tó bá fi ara da ìyà títí dé òpin tí kò sì kọ̀ mí sílẹ̀ òun ni yóò rí ìgbàlà.


“Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọn ó nawọ́ mú yín, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí yín, wọn ó mú yín lọ sí Sinagọgu, àti sínú túbú, wọn ó mú yín lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba àti àwọn ìjòyè nítorí orúkọ mi.


A ó sì kórìíra yín lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ mi.


Alábùkún fún ni ẹ̀yin, nígbà tí àwọn ènìyàn bá kórìíra yín, tí wọ́n bá yà yín kúrò nínú ẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n bá gàn yín, tí wọ́n bá ta orúkọ yín nù bí ohun búburú, nítorí ọmọ ènìyàn.


Ìbá ṣe pé èmi kò ti ṣe iṣẹ́ wọ̀n-ọn-nì láàrín wọn tí ẹlòmíràn kò ṣe rí, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n sì rí, wọ́n sì kórìíra èmi àti Baba mi.


Nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ó sì ṣe, nítorí tí wọn kò mọ Baba, wọn kò sì mọ̀ mí.


“Baba olódodo, ayé kò mọ̀ ọ́n; ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, àwọn wọ̀nyí sì mọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi.


Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Níbo ni Baba rẹ wà?” Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi: ìbá ṣe pé ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá sì ti mọ Baba mi pẹ̀lú.”


Jesu dáhùn wí pé, “Bí mo bá yin ara mi lógo, ògo mi kò jẹ́ nǹkan; Baba mi ni ẹni tí ń yìn mí lógo, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, Ọlọ́run yín ní i ṣe:


Ẹ kò sì mọ̀ ọ́n: ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n: bí mo bá sì wí pé, èmi kò mọ̀ ọ́n, èmi yóò di èké gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin: ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, mo sì pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́.


Nítorí bí mo ti ń kọjá lọ, tí mo wo àwọn ohun tí ẹ̀yin ń sìn, mo sì rí pẹpẹ kan tí a kọ àkọlé yìí sí: fún ọlọ́run àìmọ̀. Ǹjẹ́ ẹni tí ẹ̀yin ń sìn ni àìmọ̀ òun náà ni èmi ń sọ fún yin.


“Èmi tilẹ̀ rò nínú ará mi nítòótọ́ pé, ó yẹ ki èmi ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun lòdì sí orúkọ Jesu tí Nasareti.


“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, mo mọ̀ pé nípa àìmọ̀ ni ẹ̀yin fi ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àwọn olórí yín pẹ̀lú ti ṣe.


Ṣùgbọ́n kí ó má ba à tànkálẹ̀ síwájú mọ́ láàrín àwọn ènìyàn, ẹ jẹ́ kí a kìlọ̀ fún wọn pé, láti ìsinsin yìí lọ kí wọn má ṣe fi orúkọ yìí sọ̀rọ̀ sí ẹnikẹ́ni mọ́.”


Nítorí náà wọn sì lọ kúrò níwájú àjọ ìgbìmọ̀; wọn ń yọ̀ nítorí tí a kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ rẹ̀.


Ó sì gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà wá sí ìhín yìí, láti de gbogbo àwọn ti ń pe orúkọ rẹ.”


Nítorí èmi o fi gbogbo ìyà ti kò le ṣàìjẹ nítorí orúkọ mi hàn án.”


Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe:


Ẹ jí ìjí òdodo, kí ẹ má sì dẹ́ṣẹ̀; nítorí àwọn ẹlòmíràn kò ni imọ̀ Ọlọ́run, mo sọ èyí kí ojú ba à lè tiyín.


Èyí ti ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláṣẹ ayé yìí kò mọ̀. Ìbá ṣe pé wọ́n mọ̀ ọ́n, wọn kì bá tún kan Olúwa ògo mọ́ àgbélébùú.


Òun yóò fi ìyà jẹ àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí ń ṣe àìgbọ́ràn sí ìhìnrere Jesu Olúwa wa.


Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba fi fẹ́ wa, tí a fi ń pè wá ní ọmọ Ọlọ́run; bẹ́ẹ̀ ni a sá à jẹ́. Nítorí èyí ni ayé kò ṣe mọ̀ wá, nítorí tí kò mọ̀ ọ́n.


Nítorí pé, nítorí iṣẹ́ Kristi ni wọ́n ṣe jáde lọ, láìgba ohunkóhun lọ́wọ́ àwọn aláìkọlà.


Tí ìwọ sì faradà ìyà, àti nítorí orúkọ mi tí ó sì rọ́jú, tí àárẹ̀ kò sì mú ọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan