Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 14:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Filipi wí fún un pé, “Olúwa, fi Baba náà hàn wá, yóò sì tó fún wa.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Filipi sọ fún un pé, “Oluwa, fi Baba hàn wá, èyí náà sì tó wa.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Filippi wi fun u pe, Oluwa, fi Baba na hàn wa, o si to fun wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 14:8
12 Iomraidhean Croise  

Ó gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, òun sì ṣe ojúrere rẹ̀, o sì rí ojú rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀, òhun o san òdodo rẹ̀ padà fún ènìyàn.


Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa wo ojú rẹ ní òdodo; nígbà tí èmi bá jí, èmi yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí èmi bá rí àwòrán rẹ.


Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́, mo rí agbára àti ògo rẹ.


Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́, nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run.


Natanaeli béèrè pé, “Báwo ni ìwọ ti ṣe mọ̀ mí?” Jesu sì dáhùn pé, “Èmi rí ọ nígbà tí ìwọ wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ kí Filipi tó pè ọ́.”


“Nǹkan wọ̀nyí ni mo fi òwe sọ fún yín: ṣùgbọ́n àkókò dé, nígbà tí èmi kì yóò fi òwe bá yín sọ̀rọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n èmi ó sọ nípa ti Baba fún yín gbangba.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan