Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 14:11 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Ẹ gbà mí gbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, Baba sì wà nínú mi: bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ gbà mí gbọ́ nítorí àwọn ẹ̀rí iṣẹ́ náà pàápàá!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Ẹ gbà mí gbọ́ pé mo wà ninu Baba ati pé Baba wà ninu mi. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ gbà mí gbọ́ nítorí iṣẹ́ wọnyi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Ẹ gbà mi gbọ́ pe, emi wà ninu Baba, Baba si wà ninu mi: bikoṣe bẹ̃, ẹ gbà mi gbọ́ nitori awọn iṣẹ na pãpã.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 14:11
11 Iomraidhean Croise  

Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ti wí fún yín, ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́; iṣẹ́ tí èmi ń ṣe lórúkọ Baba mi, àwọn ni ó ń jẹ́rìí mi.


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere ni mo fihàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá; nítorí èwo nínú iṣẹ́ wọ̀nyí ni ẹ̀yin ṣe sọ mí ní òkúta?”


Ṣùgbọ́n bí èmi bá ṣe wọ́n, bí ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mí gbọ́, ẹ gbà iṣẹ́ náà gbọ́: kí ẹ̀yin ba à lè mọ̀, kí ó sì lè yé yín pé, Baba wà nínú mi, èmi sì wà nínú rẹ̀.”


Ìwọ kò ha gbàgbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, àti pé Baba wà nínú mi? Ọ̀rọ̀ tí èmi ń sọ fún yín, èmi kò dá a sọ; ṣùgbọ́n Baba ti ó wà nínú mi, òun ní ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀.


Ní ọjọ́ náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi wà nínú Baba mi, àti ẹ̀yin nínú mi, àti èmi nínú yín.


“Ṣùgbọ́n èmi ní ẹ̀rí tí ó pọ̀jù ti Johanu lọ: nítorí iṣẹ́ tí Baba ti fi fún mi láti ṣe parí, iṣẹ́ náà pàápàá tí èmi ń ṣe náà ń jẹ́rìí mi pé, Baba ni ó rán mi.


“Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Jesu tí Nasareti, ọkùnrin tí a mọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá nípa iṣẹ́ agbára àti tí ìyanu, àti ààmì ti Ọlọ́run ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrín yín, bí ẹ̀yin tìkára yín ti mọ̀ pẹ̀lú.


Ọlọ́run jẹ́rìí sí i nípa àwọn iṣẹ́ ààmì àti ìyanu àti oríṣìíríṣìí iṣẹ́ agbára àti nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ tí a pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan