Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 13:27 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

27 Ní kété tí Judasi gba àkàrà náà ni Satani wọ inú rẹ̀ lọ. Nítorí náà Jesu wí fún un pé, “Ohun tí ìwọ ń ṣe nì, yára ṣe é kánkán.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

27 Lẹ́yìn tí Judasi ti gba òkèlè náà, Satani wọ inú rẹ̀. Jesu bá wí fún un pé, “Tètè ṣe ohun tí o níí ṣe.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

27 Lẹhin òkele na ni Satani wọ̀ inu rẹ̀ lọ. Nitorina Jesu wi fun u pe, Ohun ti iwọ nṣe nì, yara ṣe e kánkan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 13:27
16 Iomraidhean Croise  

Ní ọ̀sán gangan, Elijah bẹ̀rẹ̀ sí ń fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà ó sì wí pé, “Ẹ kígbe lóhùn rara Ọlọ́run sá à ni òun! Bóyá ó ń ṣe àṣàrò, tàbí kò ráyè, tàbí ó re àjò. Bóyá ó sùn, ó yẹ kí a jí i.”


Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojúkọ jẹ́ kí àwọn olùfisùn dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.


Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.


Ohun búburú ni èyí jẹ́ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. Ìpín kan ṣoṣo ni ó ń dúró de gbogbo wọn, ọkàn ènìyàn pẹ̀lú kún fún ibi, ìsínwín sì wà ní ọkàn wọn nígbà tí wọ́n wà láààyè àti nígbà tí wọ́n bá darapọ̀ mọ́ òkú.


Ó béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùṣọ́ ọba wí pé, “Èéṣe tí àṣẹ ọba fi yá kánkán bẹ́ẹ̀?” Arioku sì ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ náà fún Daniẹli.


Nígbà náà ni yóò lọ, yóò sì mú ẹ̀mí méje mìíràn pẹ̀lú ara rẹ̀, tí ó burú ju òun fúnra rẹ̀ lọ. Gbogbo wọn yóò sì wá sí inú rẹ̀, wọn yóò máa gbé ibẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ọkùnrin náà a sì burú ju ìṣáájú rẹ̀ lọ; Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí fún ìran búburú yìí pẹ̀lú.”


Jesu wí fún un pé, “Padà kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Nítorí a ti kọ ọ́ pé: ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ máa sìn.’ ”


Ọmọbìnrin yìí sáré padà wá sọ́dọ̀ Herodu ọba. Ó sì wí fún un pé, “Mo ń fẹ́ orí Johanu Onítẹ̀bọmi nísinsin yìí nínú àwopọ̀kọ́.”


Satani sì wọ inú Judasi, tí à ń pè ní Iskariotu, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá.


Bí wọ́n sì ti ń jẹ oúnjẹ alẹ́, tí èṣù ti fi í sí ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni láti fi í hàn;


Kò sì sí ẹnìkan níbi tábìlì tí ó mọ ìdí tí ó ṣe sọ èyí fún un.


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin méjìlá kọ́ ni mo yàn, ọ̀kan nínú yín kò ha sì ya èṣù?”


Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Anania, Èéṣe ti Satani fi kún ọkàn rẹ láti ṣèké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí ìwọ sì fi yan apá kan pamọ́ nínú owó ilẹ̀ náà?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan