Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 12:40 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

40 “Ó ti fọ́ wọn lójú, Ó sì ti sé àyà wọn le; kí wọn má ba à fi ojú wọn rí, kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀, kí wọn má ba à yípadà, kí èmi má ba à mú wọn láradá.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

40 “Ojú wọn ti fọ́, ọkàn wọn sì ti le; kí wọn má baà fi ojú wọn ríran, kí òye má baà yé wọn. Kí wọn má baà yipada, kí n má baà wò wọ́n sàn.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

40 O ti fọ́ wọn loju, o si ti se àiya wọn le; ki nwọn má ba fi oju wọn ri, ki nwọn má ba fi ọkàn wọn mọ̀, ki nwọn má ba yipada, ki emi má ba mu wọn larada.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 12:40
44 Iomraidhean Croise  

Olúwa sì wí pé, ‘Ta ni yóò tan Ahabu láti kọlu Ramoti Gileadi? Kí ó sì tọ ikú rẹ̀ lọ níbẹ̀?’ “Ẹnìkan wí báyìí, ẹlòmíràn sì sọ òmíràn.


Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.


Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mi; wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.


Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń kú lọ; Olúwa, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira.


Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ sí ọ̀dọ̀ Farao, mo ti ṣé àyà Farao le àti àyà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kí èmi kí o ba le ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mi láàrín wọn.


Mose àti Aaroni ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí níwájú Farao, ṣùgbọ́n Olúwa sé ọkàn Farao le, òun kò sí jẹ́ kí àwọn Israẹli jáde kúrò ni orílẹ̀-èdè rẹ̀.


Nígbà náà ni èmi yóò sé ọkàn àwọn ará Ejibiti le, wọn yóò sì máa lépa wọn; Èmi yóò gba ògo fún ara mi lórí Farao; lórí gbogbo ogun rẹ̀, lórí kẹ̀kẹ́ ogun àti lórí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.


Èmi yóò sé ọkàn Farao le ti yóò fi lépa wọn. Ṣùgbọ́n èmi yóò gba ògo fún ará mi láti ìpàṣẹ Farao àti ogun rẹ̀, àti pé àwọn ará Ejibiti yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.” Àwọn Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀.


Olúwa sé ọkàn Farao ọba Ejibiti le, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọmọ Israẹli ti ń jáde lọ ní àìbẹ̀rù.


Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Ní ìgbà tí ìwọ bá padà sí Ejibiti rí i pé ìwọ ṣe iṣẹ́ ìyanu ni iwájú Farao. Èmi ti fún ọ lágbára láti ṣe é. Èmi yóò sì sé àyà rẹ̀ le, òun kì yóò jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà kí ó lọ.


Síbẹ̀ ọkàn Farao sì yigbì, kò si fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.


Ṣùgbọ́n èmi yóò sé Farao lọ́kàn le. Bí Mo tilẹ̀ ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ààmì àti ìyanu ni Ejibiti,


Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sé ọkàn Farao le, kò sì gbọ́ ti Mose àti Aaroni, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mose.


Olúwa, ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ṣùgbọ́n àwọn kò rí i. Jẹ́ kí wọ́n rí ìtara rẹ fún àwọn ènìyàn rẹ kí ojú kí ó tì wọ́n; jẹ́ kí iná tí a fi pamọ́ fún àwọn ọ̀tá rẹ jó wọn run.


Olúwa ti mú oorun ìjìká wá sórí i yín: ó ti dì yín lójú ẹ̀yin wòlíì; ó ti bo orí yín ẹ̀yin aríran.


Ṣùgbọ́n a sá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedéédéé wa a pa á lára nítorí àìṣòdodo wa; ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lórí i rẹ̀, àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi mú wa láradá.


Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì, mú kí etí wọn kí ó wúwo, kí o sì dìwọ́n ní ojú. Kí wọn kí ó má ba fi ojú wọn ríran, kí wọn kí ó má ba fi etí wọn gbọ́rọ̀, kí òye kí ó má ba yé ọkàn wọn, kí wọn kí ó má ba yípadà kí a má ba mú wọn ní ara dá.”


Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn yìí lọ kí o sì wí fún wọn pé: “ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín; ní rí rí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’


“Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́, Èmi ó wo ìpadàsẹ́yìn kúrò ní ọ̀nà títọ́ rẹ sàn.” “Bẹ́ẹ̀, ni a ó wá sọ́dọ̀ rẹ nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run wa.


Gbọ́ èyí, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n ènìyàn, tí ó lójú ti kò fi ríran tí ó létí ti kò fi gbọ́rọ̀.


“Ọmọ ènìyàn, ìwọ ń gbé ní àárín ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn. Wọ́n lójú láti fi ríran, ṣùgbọ́n wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n létí láti fi gbọ́rọ̀ ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́rọ̀, torí pé ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn ni wọ́n.


“ ‘Bí wọ́n bá sì tan wòlíì náà láti sọtẹ́lẹ̀, Èmi Olúwa ló tan wòlíì náà, Èmi yóò nawọ́ sí i, èmi yóò sì pa á run kúrò láàrín àwọn ènìyàn mi Israẹli.


“Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn, Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn.


“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Olúwa ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ṣùgbọ́n yóò mú wa láradá Ó ti pa wá lára ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa.


Ẹ fi wọ́n sílẹ̀; afọ́jú tí ń fi ọ̀nà han afọ́jú ni wọ́n. Bí afọ́jú bá sì ń fi ọ̀nà han afọ́jú, àwọn méjèèjì ni yóò jìn sí kòtò.”


Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, “ ‘wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run. Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ”


Wọn kò sá tó ni òye iṣẹ́ ìyanu ti ìṣù àkàrà, nítorí ti ọkàn wọn yigbì.


“Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi, Nítorí tí ó fi ààmì òróró yàn mí láti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì. Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àti ìmúnríran fún àwọn afọ́jú, àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́,


Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run; ṣùgbọ́n fún àwọn ẹlòmíràn wọn yóò jẹ́ òwe, pé ní rí rí, “ ‘kí wọn má ba à rí, àti ní gbígbọ́ kí ó má lè yé wọn.’


Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Isaiah sì tún sọ pé:


Jesu sì wí pé, “Nítorí ìdájọ́ ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran lè ríran; àti kí àwọn tí ó ríran lè di afọ́jú.”


Nítorí náà, bí ìjọ ti rán wọn jáde lọ sí ọ̀nà wọn, wọn la Fonisia àti Samaria kọjá, wọ́n ń ròyìn ìyípadà àwọn aláìkọlà: wọ́n sì fi ayọ̀ ńlá fún gbogbo àwọn arákùnrin.


“ ‘Tọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ, kí ó sì wí pé, “Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín; à ti ní rí rí ẹ̀yin yóò rí, ẹ̀yin kì yóò sí wòye.”


Nítorí náà ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì yípadà sí Ọlọ́run, kí a lè pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àkókò ìtura bá a lè ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,


Nítorí náà ni ó ṣe ń ṣàánú fún ẹni tí ó wù ú, ẹni tí ó wù ú a sì mú ní ọkàn le.


Ṣùgbọ́n títí di àsìkò yìí Olúwa kò fi ọkàn ìmòye tàbí ojú tí ó ń rí tàbí etí tí ó n gbọ́ fún ọ.


Nítorí Olúwa fúnrarẹ̀ ní ó sé ọkàn wọn le, kí wọn kí ó lè bá Israẹli jagun, kí òun lè pa wọ́n run pátápátá, kí wọn má sì ṣe rí ojúrere, ṣùgbọ́n kí ó lè pa wọ́n, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan