Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 12:10 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà gbìmọ̀ kí wọn lè pa Lasaru pẹ̀lú;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Àwọn olórí alufaa bá pinnu láti pa Lasaru,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Ṣugbọn awọn olori alufa gbìmọ ki nwọn le pa Lasaru pẹlu;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 12:10
14 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, tiwọn sí wí fún un pé, “Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run àwọn Heberu sọ: ‘Yóò ti pẹ́ to ti ìwọ yóò kọ̀ láti tẹrí ara rẹ ba ní iwájú mi? Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó sìn mi.


Ohun búburú ni èyí jẹ́ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. Ìpín kan ṣoṣo ni ó ń dúró de gbogbo wọn, ọkàn ènìyàn pẹ̀lú kún fún ibi, ìsínwín sì wà ní ọkàn wọn nígbà tí wọ́n wà láààyè àti nígbà tí wọ́n bá darapọ̀ mọ́ òkú.


Síbẹ̀ àwọn Farisi jáde lọ pe ìpàdé láti dìtẹ̀ mú un àti bí wọn yóò ṣe pa Jesu.


Nígbà tí Herodu rí í pé àwọn amòye náà ti tan òun jẹ, ó bínú gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà ní Bẹtilẹhẹmu àti ní ẹkùn rẹ̀ láti àwọn ọmọ ọdún méjì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àkókò tí ó ti fi ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀ béèrè lọ́wọ́ àwọn amòye náà.


“Ó sì wí fún un pé, ‘Bí wọn kò bá gbọ́ ti Mose àti ti àwọn wòlíì, a kì yóò yí wọn ní ọkàn padà bí ẹnìkan tilẹ̀ ti inú òkú dìde.’ ”


Ǹjẹ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi ti pàṣẹ pé bí ẹnìkan bá mọ ibi tí ó gbé wà, kí ó fi í hàn, kí wọn ba à lè mú un.


Nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù jáde lọ, wọ́n sì gbà Jesu gbọ́.


Nítorí náà, ìjọ ènìyàn nínú àwọn Júù ni ó mọ̀ pé ó wà níbẹ̀; wọ́n sì wá, kì í ṣe nítorí Jesu nìkan, ṣùgbọ́n kí wọn lè rí Lasaru pẹ̀lú, ẹni tí ó ti jí dìde kúrò nínú òkú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan