Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 11:39 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

39 Jesu wí pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò!” Marta, arábìnrin ẹni tí ó kú náà wí fún un pé, “Olúwa, ó ti ń rùn nísinsin yìí: nítorí pé ó di ọjọ́ kẹrin tí ó tí kú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

39 Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.” Mata, arabinrin ẹni tí ó kú, sọ fún un pé, “Oluwa, ó ti ń rùn, nítorí ó ti di òkú ọjọ́ mẹrin!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

39 Jesu wipe, Ẹ gbé okuta na kuro. Marta, arabinrin ẹniti o kú na wi fun u pe, Oluwa, o ti nrùn nisisiyi: nitoripe o di ijọ mẹrin ti o ti kú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 11:39
11 Iomraidhean Croise  

“Èmi jẹ́ àtìpó àti àlejò láàrín yín, ẹ ta ilẹ̀ ìsìnkú fún mi kí èmi le sin òkú tí ó kú fún mi sí.”


Nínú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò máa jẹun títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí inú ilẹ̀ ni a ti mú ọ jáde wá; erùpẹ̀ ilẹ̀ sá à ni ìwọ, ìwọ yóò sì padà di erùpẹ̀.”


Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkú ikú yóò jẹun lórí wọn; ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni yóò, jẹ ọba lórí wọn ní òwúrọ̀; Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́, isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn.


Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀ padà tàbí san owó ìràpadà fún Ọlọ́run.


Ní ti kí ó máa wà títí ayé láìrí isà òkú.


wọn sì ń bi ara wọn léèrè pé, “Ta ni yóò yí òkúta náà kúrò ní ẹnu ibojì fún wa?”


Nítorí náà nígbà tí Jesu dé, ó rí i pé a ti tẹ́ ẹ sínú ibojì ní ọjọ́ mẹ́rin ná,


“Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dafidi ti sin ìran rẹ tan nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́.


Nítorí tí ìwọ kí yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ni isà òkú, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.


Fún àwọn kan, àwa jẹ́ òórùn sí ikú, àti fún àwọn mìíràn òórùn ìyè sí ìyè. Ta ni ó ha si tọ́ fún nǹkan wọ̀nyí?


Ẹni tí yóò sọ ara ìrẹ̀lẹ̀ wa di ọ̀tún kí ó lè bá ara ògo rẹ̀ mu, nípa agbára tí ó mú kí ó ṣe é ṣe fún un láti tẹ orí ohun gbogbo bá fún ara rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan