Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 10:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Nítorí náà Jesu tún wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn àgùntàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Jesu tún sọ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn aguntan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Nitorina Jesu tún wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Emi ni ilẹkun awọn agutan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 10:7
12 Iomraidhean Croise  

Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa, kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé tirẹ̀ ni àwa; Àwa ní ènìyàn rẹ̀ àti àgùntàn pápá rẹ̀.


Nígbà náà àwa ènìyàn rẹ, àti àgùntàn pápá rẹ, yóò fi ọpẹ́ fún ọ títí láé; láti ìran dé ìran ni àwa ó fi ìyìn rẹ hàn.


Nítorí òun ni Ọlọ́run wa àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀, àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀. Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,


Gbogbo wa bí àgùntàn, ti ṣìnà lọ, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀; Olúwa sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀ gbogbo àìṣedéédéé wa.


Ìwọ àgùntàn mi, àgùntàn pápá mi; ni ènìyàn, èmi sì ni Ọlọ́run rẹ; ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”


Kí ó pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran fún ìrúbọ ní Jerusalẹmu ní àsìkò àjọ̀dún tí a yàn. Ìlú ti a parun yóò wá kún fún agbo àwọn ènìyàn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”


“Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí kò bá gba ẹnu-ọ̀nà wọ inú agbo àgùntàn, ṣùgbọ́n tí ó bá gba ibòmíràn gun òkè, òun náà ni olè àti ọlọ́ṣà.


Èmi ni ìlẹ̀kùn: bí ẹnìkan bá bá ọ̀dọ̀ mi wọlé, òun ni a ó gbàlà, yóò wọlé, yóò sì jáde, yóò sì rí koríko.


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba, bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.


Nítorí nípa rẹ̀ ni àwa méjèèjì ti ni àǹfààní sọ́dọ̀ baba nípa Ẹ̀mí kan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan