Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 10:24 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

24 Nítorí náà àwọn Júù wá dúró yí i ká, wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ó ti mú wa ṣe iyèméjì pẹ́ tó? Bí ìwọ bá ni Kristi náà, wí fún wa gbangba.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

24 Àwọn Juu bá pagbo yí i ká, wọ́n sọ fún un pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóo tó fi ọkàn wa balẹ̀? Bí ìwọ bá ni Mesaya, sọ fún wa pàtó.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

24 Nitorina awọn Ju wá duro yi i ká, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ó ti mu wa ṣe iyemeji pẹ to? Bi iwọ ni iṣe Kristi na, wi fun wa gbangba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 10:24
13 Iomraidhean Croise  

Elijah sì lọ síwájú gbogbo àwọn ènìyàn, ó sì wí pé, “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin yóò máa ṣiyèméjì? Bí Olúwa bá ni Ọlọ́run, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ṣùgbọ́n bí Baali bá ni Ọlọ́run, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.” Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò sì wí ohun kan.


láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣe ìwọ ni ẹni tó ń bọ̀ wá tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?”


Jesu bá wọn sọ̀rọ̀ yìí, láìfi ohunkóhun pamọ́ fún wọn, ṣùgbọ́n Peteru pe Jesu sẹ́yìn, ó sì bẹ̀rẹ̀ si bá a wí.


Bí àwọn ènìyàn sì ti ń retí, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ara wọn nítorí Johanu, bí òun ni Kristi tàbí òun kọ́;


Èyí sì ni ẹ̀rí Johanu, nígbà tí àwọn Júù rán àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi láti Jerusalẹmu wá láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ẹni tí òun ń ṣe.


Àwọn Júù sì tún mú òkúta, láti sọ lù ú.


Àwọn Júù sì dá a lóhùn pé, “Àwa kò sọ ọ́ lókùúta nítorí iṣẹ́ rere, ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀-òdì: àti nítorí ìwọ tí í ṣe ènìyàn ń fi ara rẹ pe Ọlọ́run.”


“Nǹkan wọ̀nyí ni mo fi òwe sọ fún yín: ṣùgbọ́n àkókò dé, nígbà tí èmi kì yóò fi òwe bá yín sọ̀rọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n èmi ó sọ nípa ti Baba fún yín gbangba.


Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ jẹ́?” Jesu sì wí fún un pé, “Èmi ni èyí tí mo ti wí fún yín ní àtètèkọ́ṣe.


Ìwọ ha pọ̀ ju Abrahamu Baba wa lọ, ẹni tí ó kú? Àwọn wòlíì sì kú: ta ni ìwọ ń fi ara rẹ pè?”


Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn òbí rẹ̀ sọ, nítorí tí wọ́n bẹ̀rù àwọn Júù: nítorí àwọn Júù ti fohùn ṣọ̀kan pé bí ẹnìkan bá jẹ́wọ́ pé Kristi ni, wọn ó yọ ọ́ kúrò nínú Sinagọgu.


Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fi ìgboyà púpọ̀ sọ̀rọ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan