Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 10:22 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 Àkókò náà sì jẹ́ àjọ̀dún ìyàsímímọ́ ní Jerusalẹmu, ni ìgbà òtútù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

22 Ní àkókò òtútù-nini, ó tó àkókò Àjọ̀dún Ìyàsímímọ́ Tẹmpili tí wọn ń ṣe ní Jerusalẹmu,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

22 O si jẹ ajọ ọdun iyasimimọ́ ni Jerusalemu, igba otutù ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 10:22
6 Iomraidhean Croise  

Solomoni rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa: ẹgbàá-mọ́kànlá (22,000) màlúù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ya ilé Olúwa sí mímọ́.


Ọba Solomoni sì rú ẹbọ ti ẹgbàá-mọ́kànlá (22,000), orí màlúù àti àgùntàn àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà àgùntàn àti ẹranko. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn ya ilé Ọlọ́run sí mímọ́.


Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Israẹli—àwọn àlùfáà, àwọn Lefi àti àwọn ìgbèkùn tí ó padà, ṣe ayẹyẹ yíya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀.


Àwọn olùkọ́ni ní òfin sọ̀kalẹ̀ wá láti Jerusalẹmu, wọ́n sì wí pé, “Ó ni Beelsebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù, ni ó sì fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde!”


Àwọn mìíràn wí pé, “Ìwọ̀nyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ẹ̀mí èṣù lè la ojú àwọn afọ́jú bí?”


Jesu sì ń rìn ní tẹmpili, ní ìloro Solomoni,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan