Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:42 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

42 Ó sì mú un wá sọ́dọ̀ Jesu. Jesu sì wò ó, ó wí pé, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa ni a ó sì máa pè ọ” (ìtumọ̀ èyí tí ṣe Peteru).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

42 Ó bá mú un lọ sọ́dọ̀ Jesu. Jesu tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Johanu; Kefa ni a óo máa pè ọ́.” (Ìtumọ̀ “Kefa” ni “àpáta”, “Peteru” ni ní èdè Giriki.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

42 O si mu u wá sọdọ Jesu. Jesu si wò o, o wipe, Iwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa li a o si ma pè ọ, itumọ̀ eyi ti ijẹ Peteru.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:42
20 Iomraidhean Croise  

Naamani lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ ó sì wí fún un ohun tí ọmọbìnrin Israẹli ti sọ.


Orúkọ àwọn aposteli méjèèjìlá náà ni wọ̀nyí: ẹni àkọ́kọ́ ni Simoni ẹni ti a ń pè ni Peteru àti arákùnrin rẹ̀ Anderu; Jakọbu ọmọ Sebede àti arákùnrin rẹ̀ Johanu.


Wọ̀nyí ni àwọn méjìlá náà tí ó yàn: Simoni (ẹni ti ó sọ àpèlé rẹ̀ ní Peteru)


Nígbà tí Simoni Peteru sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá eékún Jesu, ó wí pé, “Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.”


Simoni (ẹni tí a pè ní Peteru) àti Anderu arákùnrin rẹ̀, Jakọbu, Johanu, Filipi, Bartolomeu,


“Kì í ṣe ti gbogbo yín ni mo ń sọ: èmi mọ àwọn tí mo yàn: ṣùgbọ́n kí Ìwé mímọ́ bá à lè ṣẹ, ‘ẹni tí ń bá mi jẹun pọ̀ sì gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sí mi.’


Simoni Peteru, àti Tomasi tí a ń pè ní Didimu, àti Natanaeli ará Kana ti Galili, àti àwọn ọmọ Sebede, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjì mìíràn jùmọ̀ wà pọ̀.


Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ó sì padà wá sí ìhín yìí.”


Ohun tí mo ń sọ ní pé: Olúkúlùkù yín ń wí pé, “Èmí tẹ̀lé Paulu”; “Èmi tẹ̀lé Apollo” òmíràn wí pé “Èmi tẹ̀lé Kefa, Peteru”; àti ẹlòmíràn wí pé “Èmi tẹ̀lé Kristi.”


Àti pé ó farahàn Peteru, lẹ́yìn èyí, àwọn méjìlá


Ìbá ṣe Paulu, tàbí Apollo, tàbí Kefa, tàbí ayé tàbí ìyè, tàbí ikú, tàbí ohun ìsinsin yìí, tàbí ohun ìgbà tí ń bọ̀; tiyín ni gbogbo wọn.


Ṣé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú ìyàwó tí í ṣe onígbàgbọ́ káàkiri gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli mìíràn? Àti bí arákùnrin Olúwa, àti Kefa.


Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, nígbà náà ni mo gòkè lọ sì Jerusalẹmu láti lọ kì Peteru, mo sì gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní ìjọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún,


Ṣùgbọ́n nígbà tí Peteru wá sí Antioku, mo takò ó lójú ara rẹ̀, nítorí tí ó jẹ̀bi, mo sì bá a wí.


Jakọbu, Peteru, àti Johanu, àwọn ẹni tí ó dàbí ọ̀wọ́n, fún èmi àti Barnaba ni ọwọ́ ọ̀tún ìdàpọ̀ nígbà tí wọ́n rí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, wọ́n sì gbà pé kí àwa náà tọ àwọn aláìkọlà lọ, nígbà ti àwọn náà lọ sọ́dọ̀ àwọn Júù.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan