Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:3 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo; lẹ́yìn rẹ̀ a kò sì dá ohun kan nínú ohun tí a ti dá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá ohun gbogbo, ninu gbogbo ohun tí a dá, kò sí ohun kan tí a dá lẹ́yìn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Nipasẹ̀ rẹ̀ li a ti da ohun gbogbo; lẹhin rẹ̀ a ko si da ohun kan ninu ohun ti a da.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:3
20 Iomraidhean Croise  

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé.


Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a dá ènìyàn ní àwòrán ara wa, gẹ́gẹ́ bí àwa ti rí, kí wọn kí ó jẹ ọba lórí ẹja Òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, ẹran ọ̀sìn, gbogbo ilẹ̀ àti lórí ohun gbogbo tí ń rìn lórí ilẹ̀.”


Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.


Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀.


Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́, mo ń yọ̀ nígbà gbogbo níwájú rẹ̀.


Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé tí ó sì da ọmọ ènìyàn sórí i rẹ̀. Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run mo sì kó àwọn àgbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta


Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí— ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run, Òun ni Ọlọ́run; ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé, Òun ló ṣe é; Òun kò dá a láti wà lófo, ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀— Òun wí pé: “Èmi ni Olúwa, kò sì ṣí ẹlòmíràn.


Òun sì wà ní ayé, àti pé, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a sì ti dá ayé, ṣùgbọ́n ayé kò sì mọ̀ ọ́n.


Òun ni ó sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní àtètèkọ́ṣe.


Ṣùgbọ́n fún àwa Ọlọ́run kan ní ó wa, Baba, lọ́wọ́ ẹni tí ó dá ohun gbogbo, àti ti ẹni tí gbogbo wa í ṣe, àti Olúwa kan ṣoṣo Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo wà, àti àwa nípasẹ̀ rẹ̀.


àti láti mú kí gbogbo ènìyàn rí ohun tí iṣẹ́ ìríjú ohun ìjìnlẹ̀ náà jásí, èyí tí a ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́ nínú Ọlọ́run, ẹni tí ó dá ohun gbogbo nípa Jesu Kristi:


Nípa ìgbàgbọ́ ni a mọ̀ pé a ti dá ayé nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; nítorí náà kì í ṣe ohun tí o hàn ni a fi dá ohun tí a ń ri.


Olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Jesu ni Kristi, a bí i nípa ti Ọlọ́run: àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn. Ẹni tí ó bi nì, ó fẹ́ràn ẹni tí a bí nípasẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú.


“Àti sí angẹli ìjọ ní Laodikea kọ̀wé: Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ń jẹ́ Àmín wí, ẹlẹ́rìí olódodo àti olóòtítọ́, olórí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run:


“Olúwa àti Ọlọ́run, ìwọ ni o yẹ, láti gba ògo àti ọlá àti agbára: nítorí pé ìwọ ni o dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ̀ ni wọn fi wà tí a sì dá wọn.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan