Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:29 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

29 Ní ọjọ́ kejì, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

29 Ní ọjọ́ keji, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Wo ọ̀dọ́ aguntan Ọlọrun, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

29 Ni ijọ keji Johanu ri Jesu mbọ̀ wá sọdọ rẹ̀; o wipe, Wò o, Ọdọ-agutan Ọlọrun, ẹniti o kó ẹ̀ṣẹ aiye lọ!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:29
65 Iomraidhean Croise  

Kí ó wà níwájú orí Aaroni, kí ó sì lè máa ru ẹ̀bi tí ó jẹ mọ́ ẹ̀bùn mímọ́ ti àwọn ọmọ Israẹli ti yà sí mímọ́, èyíkéyìí tí ẹ̀bùn wọn lè jẹ́. Yóò máa wà níwájú orí Aaroni nígbà gbogbo, kí wọn lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa.


Síbẹ̀, ó wu Olúwa láti pa á lára àti láti mú kí ó jìyà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fi ayé rẹ̀ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayé rẹ̀ yóò pẹ́ títí, àti ète Olúwa ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀.


Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀, òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre, Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn.


A jẹ ẹ́ ní yà, a sì pọ́n ọn lójú, síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀; a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà, àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀, síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀.


Ẹ gba ọ̀rọ̀ Olúwa gbọ́, kí ẹ sì yípadà sí Olúwa. Ẹ sọ fún un pé: “Darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá kí o sì fi oore-ọ̀fẹ́ gbà wá, kí àwa kí ó lè fi ètè wa sán an fún ọ


“Èéṣe tí ẹ kò jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ní agbègbè ibi mímọ́? Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ, a fi fún yín láti lè mú ẹ̀ṣẹ̀ ìjọ ènìyàn kúrò nípa fífi ṣe ètùtù fún wọn níwájú Olúwa.


“Ní ọjọ́ náà ìsun kan yóò ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi àti fún àwọn ará Jerusalẹmu, láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìmọ́ wọn.


Olúwa sọ fún Aaroni pé, “Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ àti ìdílé baba rẹ ni yóò ru gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti dá fún ilé tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run, àti ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ nìkan ni yóò máa ru ẹ̀ṣẹ̀ iṣẹ́ àlùfáà yín.


Àwọn ọmọ Lefi ní ó gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó wà nínú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí wọ́n bá kúrò láti ṣe é. Èyí ni ìlànà láéláé fún àwọn ìran tí ó ń bọ̀. Wọn kò nígbà ogún kankan láàrín àwọn ọmọ Israẹli.


Nígbà náà ni Mose sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, Bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè.


Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;


Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;


Òun yóò sì bí ọmọkùnrin, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, nítorí òun ni yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”


Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ènìyàn kò ṣe wá sí ayé, kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, ṣùgbọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún yín, àti láti fi ẹ̀mí rẹ ṣe ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.”


Ní ọjọ́ kejì, Johanu dúró pẹ̀lú méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.


Nígbà tí ó sì rí Jesu bí ó ti ń kọjá lọ, ó wí pé, “Wò ó Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run!”


Ní ọjọ́ kejì Jesu ń fẹ́ jáde lọ sí Galili, ó sì rí Filipi, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”


Ní ọjọ́ kẹta, wọn ń ṣe ìgbéyàwó kan ní Kana ti Galili. Ìyá Jesu sì wà níbẹ̀,


“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.


Wọ́n sì wí fún obìnrin náà pé, “Kì í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ nìkan ni àwa ṣe gbàgbọ́: nítorí tí àwa tìkára wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwa sì mọ̀ pé, nítòótọ́ èyí ni Kristi náà, Olùgbàlà aráyé.”


Èmi ni oúnjẹ ìyè náà tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá: bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò yè títí láéláé: oúnjẹ náà tí èmi ó sì fi fún ni fún ìyè aráyé ni ara mi.”


Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mose.


Ibi ìwé mímọ́ tí ìwẹ̀fà náà ń kà náà ni èyí: “A fà á bí àgùntàn lọ fún pípa; àti bí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kò wí ohun kan.


Nítorí èyí tí mo rí gbà ṣáájú ohun gbogbo ní èmi pẹ̀lú ti fi lé e yín lọ́wọ́, bí Kristi ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ tí wí.


Nítorí ó tí fi í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ nítorí wa, ẹni tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ rí: kí àwa lè di òdodo Ọlọ́run nínú rẹ̀.


ẹni tí ó fi òun tìkára rẹ̀ dípò ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò nínú ayé búburú ìsinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa,


Kristi ti rà wá padà kúrò lọ́wọ́ ègún òfin, ẹni tí a fi ṣe ègún fún wa: nítorí tí a ti kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí a fi kọ́ sórí igi.”


Ẹni ti ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo ènìyàn—ẹ̀rí tí a fi fún ni ní àkókò tó yẹ.


Ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa láti rà fún ìràpadà kúrò nínú ìwà búburú gbogbo àti kí ó sì le wẹ̀ àwọn ènìyàn kan mọ́ fún ara rẹ̀ fún ìní ohun tìkára rẹ̀, àwọn tó ń ní ìtara fún iṣẹ́ rere.


Ọmọ tí í ṣe ìtànṣán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkára rẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró: Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọláńlá ní òkè.


Nítorí náà, ó yẹ pé nínú ohun gbogbo kí ó dàbí àwọn ará rẹ̀, kí ó lè jẹ́ aláàánú àti olóòtítọ́ alábojútó Àlùfáà nínú ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, kí o lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn.


Bẹ́ẹ̀ ni Kristi pẹ̀lú lẹ́yìn tí a ti fi rú ẹbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láti ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, yóò farahàn ní ìgbà kejì láìsí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí n wo ọ̀nà rẹ̀ fún ìgbàlà.


Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí i ti ọ̀dọ́-àgùntàn ti kò lábùkù, tí kò sì lábàwọ́n, àní, ẹ̀jẹ̀ Kristi.


Ẹni tí òun tìkára rẹ̀ fi ara rẹ̀ ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi àgbélébùú, pé kí àwa lè di òkú sí ẹ̀ṣẹ̀, ki a sì di ààyè sí òdodo: nípa ìjìyà ẹni tí ó mú yín láradá.


Nítorí tí Kristi pẹ̀lú jìyà lẹ́ẹ̀kan nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòótọ́ fún àwọn aláìṣòótọ́, kí a lè mú wa dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí a pa nínú ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí:


Òun sì ní ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, kì í tilẹ̀ ṣe fún tiwa nìkan ṣùgbọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo aráyé.


Ẹ̀yin sì mọ̀ pé, òun farahàn láti mu ẹ̀ṣẹ̀ kúrò; ẹ̀ṣẹ̀ kò sì ṣí nínú rẹ̀.


Nínú èyí ni ìfẹ́ wà, kì í ṣe pé àwa fẹ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n òun fẹ́ wá, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa.


àti láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí olóòtítọ́, àkọ́bí nínú àwọn òkú, àti aláṣẹ àwọn ọba ayé. Ẹni tí ó fẹ́ wa, ẹni tí ó gbà wá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀,


Wọ́n sì ti ṣẹ́gun rẹ̀ nítorí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùntàn náà, àti nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn, wọn kò sì fẹ́ràn ẹ̀mí wọn àní títí dé ikú.


Gbogbo àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì máa sìn ín, olúkúlùkù ẹni tí a kò kọ orúkọ rẹ̀, sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-Àgùntàn tí a tí pa láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.


Mo sì wo, si kíyèsi i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà dúró lórí Òkè Sioni, àti pẹ̀lú rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì (144,000) ènìyàn; wọ́n ní orúkọ rẹ̀, àti orúkọ baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn.


Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ sínú ago ìrunú rẹ̀; a ó sì fi iná sulfuru dá a lóró níwájú àwọn angẹli mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn:


Àwọn wọ̀nyí ni a kò fi obìnrin sọ di èérí: nítorí tí wọ́n jẹ́ wúńdíá. Àwọn wọ̀nyí ni o ń tọ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà lẹ́yìn níbikíbi tí o bá ń lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a rà padà láti inú àwọn ènìyàn wá, wọ́n jẹ́ àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà.


Wọ́n sì ń kọ orin ti Mose, ìránṣẹ́ Ọlọ́run, àti orin ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn, wí pé: “Títóbi àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè; òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀nà rẹ̀, ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè.


Àwọn wọ̀nyí ni yóò si máa bá Ọ̀dọ́-Àgùntàn jagun, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà yóò sì ṣẹ́gun wọn: nítorí òun ni Olúwa àwọn Olúwa, àti ọba àwọn ọba: Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀, tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olóòtítọ́ yóò sì ṣẹ́gun pẹ̀lú.”


Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi, kí a sì fi ògo fún un. Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé, aya rẹ̀ sì ti múra tán.


Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’ ” Ó sì wí fún mi pé: “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.”


Odi ìlú náà sì ni ìpìlẹ̀ méjìlá, àti lórí wọn orúkọ àwọn Aposteli méjìlá tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn.


Ohun aláìmọ́ kan ki yóò sì wọ inú rẹ̀ rárá, tàbí ohun tí ń ṣiṣẹ́ ìríra àti èké; bí kò ṣe àwọn tí a kọ sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-àgùntàn.


Ọ̀kan nínú àwọn angẹli méje, tí wọ́n ni ago méje, tí ó kún fún ìyọnu méje ìkẹyìn sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìn-ín, èmi ó fi ìyàwó, aya Ọ̀dọ́-àgùntàn hàn ọ́.”


Mo sì rí Ọ̀dọ́-Àgùntàn ni àárín ìtẹ́ náà, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti ni àárín àwọn àgbà náà, Ọ̀dọ́-àgùntàn kan dúró bí èyí tí a ti pa, ó ní ìwo méje àti ojú méje, tí o jẹ́ Ẹ̀mí méje tí Ọlọ́run, tí a rán jáde lọ sì orí ilẹ̀ ayé gbogbo.


Nígbà tí ó sì gba ìwé náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn náà, olúkúlùkù wọn mú ohun èlò orin olókùn kan lọ́wọ́, àti ago wúrà tí ó kún fún tùràrí tí i ṣe àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́.


Èmi sì rí i nígbà tí Ọ̀dọ́-àgùntàn náà ṣí ọkàn nínú èdìdì wọ̀nyí, mo sì gbọ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ń wí bí sísán àrá pé, “Wá, wò ó!”


Wọ́n sì ń wí fún àwọn òkè àti àwọn àpáta náà pé, “Ẹ wó lù wá, kí ẹ sì fi wá pamọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti kúrò nínú ìbínú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà:


Mo sì wí fún un pé, “Olúwa mi, ìwọ ni o lè mọ̀.” Ó sì wí fún mí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni o jáde láti inú ìpọ́njú ńlá, wọ́n sì fọ aṣọ wọ́n, wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà.


Nítorí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń bẹ ni àárín ìtẹ́ náà ni yóò máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn wọn, ‘tí yóò sì máa ṣe amọ̀nà wọn sí ibi orísun omi ìyè:’ ‘Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn.’ ”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan