Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:28 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

28 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣẹlẹ̀ ní Betani ní òdìkejì odò Jordani, níbi tí Johanu ti ń fi omi bamitiisi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

28 Ní Bẹtani tí ó wà ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani ni nǹkan wọnyi ti ṣẹlẹ̀, níbi tí Johanu ti ń ṣe ìrìbọmi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

28 Nkan wọnyi li a ṣe ni Betani loke odò Jordani, nibiti Johanu gbé mbaptisi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:28
6 Iomraidhean Croise  

Ní ọjọ́ kejì Jesu ń fẹ́ jáde lọ sí Galili, ó sì rí Filipi, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”


Ó sì tún kọjá lọ sí apá kejì Jordani sí ibi tí Johanu ti kọ́kọ́ ń bamitiisi; níbẹ̀ ni ó sì jókòó.


“Èéṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn tálákà?”


Johanu pẹ̀lú sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi ní Aenoni, ní agbègbè Salimu, nítorí tí omi púpọ̀ wà níbẹ̀: wọ́n sì ń wá, a sì ń tẹ̀ ẹ́ wọn bọ omi.


Wọ́n sì tọ Johanu wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Rabbi, ẹni tí ó ti wà pẹ̀lú rẹ lókè odò Jordani, tí ìwọ ti jẹ́rìí rẹ̀, wò ó, òun tẹ àwọn ènìyàn bọ omi, gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá.”


Gideoni tún ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè Efraimu wí pé, “Ẹ jáde wá bá àwọn ará Midiani jà, kí ẹ tètè gba àwọn omi Jordani títí dé Beti-Bara kí wọ́n tó dé bẹ̀.” Báyìí ni a ṣe pe gbogbo ọkùnrin ológun Efraimu jáde tí wọ́n sì gba gbogbo àwọn à bá wọ odò Jordani títí dé Beti-Bara.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan