Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:17 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

17 Nítorí pé nípasẹ̀ Mose ni a ti fi òfin fún ni ṣùgbọ́n òun; oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ láti ipasẹ̀ Jesu Kristi wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

17 Nípasẹ̀ Mose ni a ti fún wa ní Òfin, ṣugbọn nípasẹ Jesu Kristi ni oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́ ti wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

17 Nitoripe nipasẹ Mose li a ti fi ofin funni, ṣugbọn ore-ọfẹ ati otitọ tipasẹ Jesu Kristi wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:17
37 Iomraidhean Croise  

àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó ti bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nítorí tí ìwọ gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu.”


Èmi yóò sì fi ọ̀tá sí àárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà; òun yóò fọ́ orí rẹ, ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”


Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀; òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn.


Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli; gbogbo òpin ayé ni ó ti rí iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.


Ìwọ yóò fi òtítọ́ hàn sí Jakọbu ìwọ yóò sì fi àánú hàn sí Abrahamu, bí ìwọ ṣe búra fún àwọn baba wa láti ọjọ́ ìgbàanì.


Ọ̀rọ̀ náà sì di ara, òun sì ń bá wa gbé. Àwa sì ti rí ògo rẹ̀, àní ògo ọmọ rẹ kan ṣoṣo, tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba, bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.


Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “ọba ni ọ́ nígbà náà?” Jesu dáhùn wí pé, “Ìwọ wí pé, ọba ni èmi jẹ́. Nítorí èyí ni a ṣe bí mí, àti nítorí ìdí èyí ni mo sì ṣe wá sí ayé kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́, olúkúlùkù ẹni tí í ṣe ti òtítọ́ ń gbọ́ ohùn mi.”


“Ẹ má ṣe rò pé, èmi ó fi yín sùn lọ́dọ̀ Baba: ẹni tí ń fi yín sùn wà, àní Mose, ẹni tí ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lé.


Mose kò ha fi òfin fún yín, kò sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó pa òfin náà mọ́? Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá ọ̀nà láti pa mí?”


Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira.”


Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run bá Mose sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti eléyìí, àwa kò mọ ibi tí ó ti wá.”


Àwọn fi ẹnu kò lórí ọjọ́ tí wọn yóò ṣe ìpàdé pẹ̀lú Paulu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni ó tọ̀ ọ́ wa ni ilé àgbàwọ̀ rẹ̀; àwọn ẹni tí òun sọ àsọyé ọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún, ó ń yí wọn padà nípa ti Jesu láti inú òfin Mose àti àwọn wòlíì, láti òwúrọ̀ títí ó fi di àṣálẹ́.


Èyí náà ni ẹni tí ó wà nínú ìjọ ní ijù pẹ̀lú angẹli náà tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sinai, àti pẹ̀lú àwọn baba wa; ẹni ti ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti fi fún wa.


Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kì yóò tún ní ipá lórí yín mọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí lábẹ́ ìdè òfin, bí kò ṣe lábẹ́ oore-ọ̀fẹ́.


Nítorí tí gbogbo ìlérí Ọlọ́run dí bẹ́ẹ̀ ni nínú Kristi. Nítorí ìdí èyí ní a ṣe ń wí pé “Àmín” nípasẹ̀ rẹ̀ sí ògo Ọlọ́run.


Èyí tí mò ń wí ni pé: májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níṣàájú, òfin ti ó dé lẹ́yìn ọgbọ̀n-lé-nírinwó ọdún kò lè sọ ọ́ di asán, kí ó sì mú ìlérí náà di aláìlágbára.


òfin tí Mose fi fún wa, ìní ti ìjọ ènìyàn Jakọbu.


Èyí ni òfin tí Mose gbé kalẹ̀ fún àwọn ará Israẹli.


Mose sì pe gbogbo Israẹli jọ, ó sì wí pé: Gbọ́ ìwọ Israẹli, gbọ́ ìlànà àti òfin tí mo mú wá sí etí ìgbọ́ ọ yín lónìí. Ẹ kọ wọ́n, kí ẹ sì ri dájú pé ẹ̀ ń ṣe wọ́n.


Ó sì fẹ́rẹ̀ jẹ́ ohun gbogbo ni a fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀nù gẹ́gẹ́ bí òfin; àti pé láìsí ìtàjẹ̀ sílẹ̀ kò sí ìdáríjì.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan