Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joẹli 3:3 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Wọ́n si ti di ìbò fún àwọn ènìyàn mi; wọ́n sì ti fi ọmọdékùnrin kan fún panṣágà obìnrin kan, wọ́n sì ta ọmọdébìnrin kan fún ọtí wáìnì, kí wọ́n kí ó lè mu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Wọ́n ti ṣẹ́ gègé lórí àwọn eniyan mi, wọ́n ti ta àwọn ọmọkunrin wọn, wọ́n fi owó wọn san owó aṣẹ́wó, wọ́n sì ta àwọn ọmọbinrin wọn, wọ́n fi owó wọn ra ọtí waini.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Nwọn si ti di ibò fun awọn enia mi; nwọn si ti fi ọmọdekunrin kan fun panṣagà obinrin kan, nwọn si ti tà ọmọdebinrin kan fun ọti-waini, ki nwọn ki o le mu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joẹli 3:3
8 Iomraidhean Croise  

Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba, ẹ̀yin sì da iye lé ọ̀rẹ́ yín.


“ ‘Àwọn ará Giriki, Tubali, Jafani àti Meṣeki, ṣòwò pẹ̀lú rẹ: wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàṣípàrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ.


Ẹ jí gbogbo ẹ̀yin ọ̀mùtí kí ẹ sì sọkún ẹ hu gbogbo ẹ̀yin ọ̀mu-wáìnì; ẹ hu nítorí wáìnì tuntun nítorí a gbà á kúrò lẹ́nu yín.


Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Israẹli àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Wọ́n ta olódodo fún fàdákà àti aláìní fún bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì.


Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apá kan, ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ, tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹ tí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jerusalẹmu, ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn.


Síbẹ̀síbẹ̀ a kó o ní ìgbèkùn o sì lọ sí oko ẹrú. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ̀ ni a ó fọ́ mọ́lẹ̀ ní orí ìta gbogbo ìgboro. Wọ́n sì di ìbò nítorí àwọn ọlọ́lá rẹ̀ ọkùnrin, gbogbo àwọn ọlọ́lá rẹ ni a sì fi ẹ̀wọ̀n dè


Àti ti Kinamoni, àti ti onírúurú ohun olóòórùn dídùn, àti ti ohun ìkunra, àti tí tùràrí, àti ti ọtí wáìnì, àti ti òróró, àti ti ìyẹ̀fun dáradára, àti ti alikama, àti ti ẹran ńlá, àti ti àgùntàn, àti ti ẹṣin, àti ti kẹ̀kẹ́, àti ti ẹrú, àti ti ọkàn ènìyàn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan