Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Jeremiah 1:2 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ ọ́ wá ní ọdún kẹtàlá ní àkókò ìjọba Josiah ọmọ Amoni ọba Juda,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Nígbà ayé Josaya, ọmọ Amoni, ọba Juda, ní ọdún kẹtala tí Josaya gun orí oyè ni OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Ẹniti ọ̀rọ Oluwa tọ̀ wá ni igba ọjọ Josiah, ọmọ Amoni, ọba Juda, li ọdun kẹtala ijọba rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Jeremiah 1:2
18 Iomraidhean Croise  

Ó sì kígbe sí pẹpẹ náà nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé, “Pẹpẹ! Pẹpẹ! Báyìí ni Olúwa wí: ‘A ó bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Josiah ní ilé Dafidi. Lórí rẹ ni yóò sì fi àwọn àlùfáà ibi gíga wọ̀n-ọn-nì tí ń fi tùràrí lórí rẹ̀ rú ẹbọ, a ó sì sun egungun ènìyàn lórí rẹ.’ ”


Bí wọ́n sì ti jókòó ti tábìlì, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ wòlíì tí ó mú un padà wá pé;


Manase sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ọgbà ààfin rẹ̀, ọgbà Ussa. Amoni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.


Nígbà náà àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tí ó dìtẹ̀ sí ọba Amoni, wọ́n sì fi Josiah ọmọ rẹ̀ jẹ ọba ní ààyè rẹ̀.


Ní ọdún kejì-dínlógún tí ó fi jẹ ọba. Ọba Josiah rán akọ̀wé, Ṣafani ọmọ Asalia, ọmọ Meṣullamu, sí ilé Olúwa. Ó wí pé;


Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ mí wá wí pé: “Kí ni o rí Jeremiah?” Mo sì dáhùn wí pé “Mo rí ẹ̀ka igi almondi.”


Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé,


Fún odidi ọdún mẹ́tàlélógún, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún kẹtàlá Josiah, ọmọ Amoni ọba Juda, títí di ọjọ́ yìí, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, mo sì ti sọ ọ́ fún un yín láti ìgbà dé ìgbà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetísílẹ̀.


Láìpẹ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wòlíì wá lẹ́yìn ìgbà tí wòlíì Hananiah ti gbé àjàgà kúrò ní ọrùn wòlíì Jeremiah wí pé:


Ní àkókò ìjọba Josiah ọba, Olúwa wí fún mi pé, “Ṣé o ti rí nǹkan tí àwọn Israẹli aláìnígbàgbọ́ ti ṣe? Wọ́n ti lọ sí àwọn òkè gíga àti sí abẹ́ àwọn igi, wọ́n sì ti ṣe àgbèrè níbẹ̀.


“Mú ìwé kíká fún ará rẹ, kí o sì kọ sínú rẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ nípa Israẹli àti ti Juda, àti sí gbogbo orílẹ̀-èdè láti ìgbà tí mo ti sọ fún ọ láti ọjọ́ Josiah títí di òní.


Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Hosea ọmọ Beeri wá ní àkókò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah; àwọn ọba Juda àti ní àkókò ọba Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi ní Israẹli:


Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Joẹli ọmọ Petueli wá.


Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jona ọmọ Amittai wá, wí pé:


Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Mika ará Moreṣeti wá ní àkókò ìjọba Jotamu, Ahasi, àti Hesekiah, àwọn ọba Juda nìwọ̀nyí, ìran tí ó rí nípa Samaria àti Jerusalẹmu.


Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Sefaniah ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedaliah, ọmọ Amariah, ọmọ Hesekiah, ní ìgbà Josiah ọmọ Amoni ọba Juda.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan