Ìfihàn 8:3 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní3 Angẹli mìíràn sì wá, ó sì dúró ti pẹpẹ, ó ní àwo tùràrí wúrà kan a sì fi tùràrí púpọ̀ fún un, láti máa fi kún àdúrà gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ lórí pẹpẹ, pẹpẹ wúrà tí ń bẹ níwájú ìtẹ́. Faic an caibideilYoruba Bible3 Angẹli mìíràn tún dé, ó dúró lẹ́bàá pẹpẹ ìrúbọ. Ó mú àwo turari tí wọ́n fi wúrà ṣe lọ́wọ́. A fún un ní turari pupọ kí ó fi rúbọ pẹlu adura gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun lórí pẹpẹ ìrúbọ wúrà tí ó wà níwájú ìtẹ́ náà. Faic an caibideilBibeli Mimọ3 Angẹli miran si wá, o si duro tì pẹpẹ, o ni awo turari wura kan; a si fi turari pupọ̀ fun u, ki o le fi i kún adura gbogbo awọn enia mimọ́ lori pẹpẹ wura ti mbẹ niwaju itẹ́. Faic an caibideil |