Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Ìfihàn 8:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì keje, ìdákẹ́rọ́rọ́ sì wà ní ọ̀run níwọ̀n ààbọ̀ wákàtí kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Nígbà tí Ọ̀dọ́ Aguntan náà tú èdìdì keje, gbogbo ohun tí ó wà ní ọ̀run parọ́rọ́ fún bí ìdajì wakati kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 NIGBATI o si ṣí èdidi keje, kẹ́kẹ́ pa li ọrun niwọn àbọ wakati kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Ìfihàn 8:1
14 Iomraidhean Croise  

Ó dúró jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n èmi kò le wo àpẹẹrẹ ìrí rẹ̀, àwòrán kan hàn níwájú mi, ìdákẹ́rọ́rọ́ wà, mo sì gbóhùn kan wí pé:


Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa, kí o sì fi sùúrù dúró dè é; má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn, nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.


Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi; ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.


Ṣùgbọ́n Olúwa wà nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀; Ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ.


Ẹ̀ dákẹ́, gbogbo ẹran-ara níwájú Olúwa: nítorí a jí i láti ibùgbé mímọ́ rẹ̀ wá.”


Nítorí náà wọ́n lọ. Wọ́n sì ṣé òkúta ibojì náà dáradára. Wọ́n sì fi àwọn olùṣọ́ sí ibẹ̀ láti dáàbò bò ó.


Mo sì rí i ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, ìwé kan ti a kọ nínú àti lẹ́yìn, ti a sì fi èdìdì méje dí.


Wọn sì ń kọ orin tuntun kan, wí pé: “Ìwọ ní o yẹ láti gba ìwé náà, àti láti ṣí èdìdì rẹ̀: nítorí tí a tí pa ọ, ìwọ sì tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe ìràpadà ènìyàn sí Ọlọ́run láti inú ẹ̀yà gbogbo, àti èdè gbogbo, àti inú ènìyàn gbogbo, àti orílẹ̀-èdè gbogbo wá:


Èmi sì rí i nígbà tí Ọ̀dọ́-àgùntàn náà ṣí ọkàn nínú èdìdì wọ̀nyí, mo sì gbọ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ń wí bí sísán àrá pé, “Wá, wò ó!”


Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹfà mo sì rí i, sì kíyèsi i, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá kan ṣẹ̀; oòrùn sì dúdú bí aṣọ ọ̀fọ̀ onírun, òṣùpá sì dàbí ẹ̀jẹ̀;


Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kejì, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè wí pé, “Wá, wò ó!”


Nígbà tí ó sì di èdìdì kẹta, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kẹta wí pé, “Wá wò ó”. Mo sì wò ó, sì kíyèsi i, ẹṣin dúdú kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ní ìwọ̀n aláwẹ́ méjì ní ọwọ́ rẹ̀.


Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹrin, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kan wí pé, Wá wò ó.


Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì karùn-ún, mo rí lábẹ́ pẹpẹ, ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí tí wọ́n dìímú:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan