Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Ìfihàn 2:3 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Tí ìwọ sì faradà ìyà, àti nítorí orúkọ mi tí ó sì rọ́jú, tí àárẹ̀ kò sì mú ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 O ní ìfaradà. O ti farada ìyà nítorí orúkọ mi, o kò sì jẹ́ kí àárẹ̀ mú ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ti iwọ si farada ìya, ati nitori orukọ mi ti o si fi aiya rán, ti ãrẹ̀ kò si mu ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Ìfihàn 2:3
49 Iomraidhean Croise  

Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa, kí o sì fi sùúrù dúró dè é; má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn, nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.


Nítorí rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn, ìtìjú sì bo ojú mi.


Nítorí èmi ti dẹ́ṣẹ̀ sí i, Èmi yóò faradà ìbínú Olúwa, títí òun yóò ṣe gba ẹjọ́ mi rò, tí yóò sì ṣe ìdájọ́ mi. Òun yóò sì mú mi wá sínú ìmọ́lẹ̀; èmi yóò sì rí òdodo rẹ̀.


Wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń kọjá lọ. Simoni ará Kirene. Òun ni baba Aleksanderu àti Rufusi. Wọ́n sì mú un ní tipátipá, pé kí ó rú àgbélébùú Jesu.


Ẹnikẹ́ni tí kò bá ru àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.


Ó sì pa òwe kan fún wọn láti fi yé wọn pe, ó yẹ kí a máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí a má sì ṣàárẹ̀;


Nínú ìdúró ṣinṣin yín ni ẹ̀yin ó jèrè ọkàn yín.


Simoni sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́ni, gbogbo òru ni àwa fi ṣiṣẹ́, àwa kò sì mú nǹkan kan: ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀ rẹ èmi ó ju àwọ̀n náà sí ìsàlẹ̀.”


Ṣùgbọ́n ti ilẹ̀ rere ni àwọn tí wọ́n fi ọkàn òtítọ́ àti rere gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n dìímú ṣinṣin, wọ́n sì fi sùúrù so èso.


Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n yóò ṣe sí yín, nítorí orúkọ mi, nítorí tí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi.


Ẹ máa yọ̀ ni ìrètí; ẹ máa mú sùúrù nínú ìpọ́njú; ẹ máa dúró gbọingbọin nínú àdúrà.


Ẹ kí Trifena àti Trifosa, àwọn obìnrin tí wọ́n ṣe iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa. Ẹ kí Persi ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, obìnrin mìíràn tí ó ṣe iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa.


Àwọn ẹni tí ń fi sùúrù nínú rere ṣíṣe, wá ògo àti ọlá àti àìdíbàjẹ́ ni yóò fi ìyè àìnípẹ̀kun fún.


Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń retí èyí tí àwa kò rí, ǹjẹ́ àwa ń fi sùúrù dúró dè é.


A máa faradà ohun gbogbo sí òtítọ́, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fàyàrán ohun gbogbo.


Kí ẹ̀yin tẹríba fún irú àwọn báwọ̀nyí, àti fún olúkúlùkù olùbáṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú wa tí ó sì ń ṣe làálàá.


Àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, èyí nì, lórí iṣẹ́ ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n àwa ní ìrètí pé, bí ìgbàgbọ́ yín ti ń dàgbà sí i, gẹ́gẹ́ bí ààlà wa, àwa ó dí gbígbéga lọ́dọ̀ yín sí i lọ́pọ̀lọpọ̀.


Ìránṣẹ́ Kristi ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọpọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbàkúgbà, ní ti fífẹ́rẹ kú nígbà púpọ̀.


Nítorí náà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé nípa àánú Ọlọ́run ni a rí iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí gba, àárẹ̀ kò mú ọkàn wa rara;


Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa; ṣùgbọ́n bí ọkùnrin ti òde wa bá ń parun, síbẹ̀ ọkùnrin tí inú wa ń di tuntun lójoojúmọ́.


Nítorí náà àwa ń ṣakitiyan, pé, bí àwa bá wà ní ilé tàbí bí a kò sí, kí àwa lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.


nípa nínà, nínú túbú, nínú ìrúkèrúdò, nínú iṣẹ́ àṣekára, nínú àìsàn, nínú ìgbààwẹ̀.


Ẹ máa ru ẹrù ọmọnìkejì yín, kí ẹ sì fi bẹ́ẹ̀ mú òfin Kristi ṣẹ.


Ẹ má sì jẹ́ kí àárẹ̀ ọkàn mú wa ní ṣíṣe rere, nítorí tí a ó kórè nígbà tí àkókò bá dé, bí a kò bá ṣe àárẹ̀.


Bí ẹ sì ṣe di ọ̀rọ̀ ìyè mú gírígírí, kí èmi lè ṣògo ni ọjọ́ Kristi pé èmi kò sáré lásán, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ṣe làálàá lásán.


Mo sì bẹ̀ yin pẹ̀lú bí alájọru àjàgà mi tòótọ́, ran àwọn obìnrin wọ̀nyí lọ́wọ́, nítorí wọn bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìfẹ̀gbẹ́-kẹ̀gbẹ́ nínú ìhìnrere, àti Klementi pẹ̀lú, àti àwọn olùbáṣiṣẹ́ mi yòókù pẹ̀lú, orúkọ àwọn tí ń bẹ nínú ìwé ìyè.


pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀síwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀.


A ń rántí yin ni àìsimi nígbà gbogbo níwájú Ọlọ́run àti Baba nípa iṣẹ́ ìgbàgbọ́ yín, iṣẹ́ ìfẹ́ yín àti ìdúró ṣinṣin ìrètí yín nínú Jesu Kristi Olúwa wa.


Nítòótọ́ ẹ rántí, ará, iṣẹ́ àti làálàá wa; lọ́sàn án àti lóru ni àwa ń ṣiṣẹ́ kí ìnáwó wa má bà á di ìṣòro fún ẹnikẹ́ni bí a ti ń wàásù ìhìnrere Ọlọ́run fún un yín.


Ẹ̀yin ará, ẹ fi ọlá fún àwọn olórí tí ń ṣe iṣẹ́ àṣekára láàrín yín tí wọn ń kìlọ̀ fún yín nínú Olúwa.


Ṣùgbọ́n ní tiyín ará, ẹ má ṣe jẹ́ kí agara dá yín ní rere ṣíṣe.


Kí Olúwa máa tọ́ ọkàn yín ṣọ́nà sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti sínú sùúrù Kristi.


Bẹ́ẹ̀ ni àwa kò sì jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, àwa ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru kí a má ba à di àjàgà sí ẹnikẹ́ni nínú yín lọ́rùn.


Nítorí fún èyí ni àwa ń ṣe làálàá tí a sì ń jìjàkadì, nítorí àwa ní ìrètí nínú Ọlọ́run alààyè, ẹni tí í ṣe Olùgbàlà gbogbo ènìyàn, pẹ̀lúpẹ̀lú ti àwọn ti ó gbàgbọ́.


Àwọn alàgbà ti ó ṣe àkóso dáradára ni kí a kà yẹ sí ọlá ìlọ́po méjì, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ti ó ṣe làálàá ni ọ̀rọ̀ àti ni kíkọ́ni.


Nítorí ẹ̀yin kò le ṣe aláìní sùúrù, nítorí ìgbà tí ẹ̀yin bá ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tan kí ẹ̀yin le gba ìlérí náà.


Nítorí náà bí a ti fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ tí o kún fún àwọn ẹlẹ́rìí tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apá kan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa,


Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a jáde tọ̀ ọ́ lọ lẹ́yìn ibùdó, kí a máa ru ẹ̀gàn rẹ̀.


Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yin àti ìfẹ́ tí ẹ̀yin fihàn sí orúkọ rẹ̀, nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ẹ ti ṣe fún àwọn ènìyàn mímọ́, tí ẹ sì tún ń ṣe.


Kí ẹ má ṣe di onílọ̀ra, ṣùgbọ́n aláfarawé àwọn tí wọn ti ipa ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí.


Bẹ́ẹ̀ náà sì ni, lẹ́yìn ìgbà tí Abrahamu fi sùúrù dúró, ó ri ìlérí náà gbà.


àti àìrékọjá kún ìmọ̀; àti sùúrù kún àìrékọjá; àti ìwà-bí-Ọlọ́run kún sùúrù.


Èmi, Johanu, arákùnrin yín àti alábápín pẹ̀lú yín nínú wàhálà àti ìjọba àti sùúrù tí ń bẹ nínú Jesu, wà ní erékúṣù tí a ń pè ní Patmo, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí Jesu Kristi.


Nítorí tí ìwọ tí pa ọ̀rọ̀ sùúrù mi mọ́, èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, tí ń bọ̀ wá dé bá gbogbo ayé, láti dán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé wò.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan