Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 8:2 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Gbogbo ìsun ibú àti fèrèsé ìṣàn ọ̀run tì, òjò pẹ̀lú sì dáwọ́ rírọ̀ dúró.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ọlọrun sé orísun omi tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀, ó ti àwọn fèrèsé ojú ọ̀run, òjò náà sì dá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 A si dí gbogbo isun ibú ati awọn ferese ọrun, o si mu òjo dá lati ọrun wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 8:2
10 Iomraidhean Croise  

Ní ọjọ́ kẹtà-dínlógún oṣù kejì, tí Noa pé ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún, ni gbogbo ìsun ibú ya, fèrèsé ìṣàn omi ọ̀run sì ṣí sílẹ̀.


Òjò àrọ̀ìrọ̀dá sì rọ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.


Nítorí ní ọjọ́ méje sí ìhín, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi yóò sì pa gbogbo ohun alààyè tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀.”


“Ìwọ ha wọ inú ìsun Òkun lọ rí bí? Ìwọ sì rìn lórí ìsàlẹ̀ ibú ńlá?


Ta ni ó fi ọgbọ́n ka iye àwọsánmọ̀? Ta ni ó sì mú ìgò ọ̀run dà jáde,


Nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfúrufú lókè tí ó sì fi orísun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹsẹ̀,


Nítorí tí ìwọ ti sọ mí sínú ibú, ní àárín Òkun, ìṣàn omi sì yí mi káàkiri; gbogbo bíbì omi àti rírú omi rékọjá lórí mi.


Ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ sá ni èmi, èmi sí ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi. Bí mo wí fún ẹni kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ, àti fún ẹni kejì pé, ‘Wá,’ a sì wá, àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan