Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 8:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ọlọ́run sì rántí Noa àti ohun alààyè gbogbo tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, bí àwọn ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn, ó sì mú kí afẹ́fẹ́ fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì fà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Ṣugbọn Ọlọrun ranti Noa, ati gbogbo ẹranko, ati ẹran ọ̀sìn tí ó wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀. Nítorí náà, Ọlọrun mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 ỌLỌRUN si ranti Noa, ati ohun alãye gbogbo, ati gbogbo ẹran-ọ̀sin ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀: Ọlọrun si mu afẹfẹ kọja lori ilẹ, omi na si fà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 8:1
35 Iomraidhean Croise  

Ọlọ́run sì rántí Abrahamu, nígbà tí ó run ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì tan, ó sì mú Lọti jáde kúrò láàrín ìparun náà, tí ó kọlu ìlú tí Lọti ti gbé.


Nígbà náà ni Ọlọ́run rántí Rakeli, Ọlọ́run sì gbọ́ tirẹ̀, ó sì ṣí i ní inú.


Àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, ìbá à ṣe ẹyẹ, ẹja, ẹran ọ̀sìn, ẹranko igbó, gbogbo ohun tí ó jáde kúrò nínú ọkọ̀ pẹ̀lú yín, àní gbogbo ẹ̀dá alààyè ní ayé.


Rántí ì mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o má sì ṣe gbàgbé ohun tí mo fi òtítọ́ ṣe fún ilé Ọlọ́run mi yìí àti fún iṣẹ́ ẹ rẹ̀ gbogbo.


Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi pé kí wọn ya ara wọn sí mímọ́, kí wọn sì ṣọ́ ẹnu ibodè kí a lè pa ọjọ́ ìsinmi mọ́. Tún rántí mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o sì fi àánú un rẹ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí i títóbi ìfẹ́ ẹ̀ rẹ.


Rántí wọn, Ọlọ́run mi, nítorí wọ́n ti ba iṣẹ́ àlùfáà jẹ́ pẹ̀lú májẹ̀mú iṣẹ́ àlùfáà àti ti àwọn Lefi.


Mo sì tún pèsè fún ọrẹ, igi—pákó ní àkókò tí a yàn àti fún àwọn èso àkọ́so. Rántí mi fún rere, Ọlọ́run mi.


Kíyèsi i, ó dá àwọn omi dúró, wọ́n sì gbẹ; Ó sì rán wọn jáde, wọ́n sì ṣẹ̀ bo ilẹ̀ ayé yípo.


“Háà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú, kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀, títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá, ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi!


Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ rẹ̀ àti Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀.


Rántí mi, Olúwa, Nígbà tí o bá fi ojúrere rẹ hàn, wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n,


Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Israẹli; yóò bùkún ilé Aaroni.


Olúwa, rántí Dafidi nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.


Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.


Olúwa rántí ọjọ́ Jerusalẹmu, lára àwọn ọmọ Edomu, àwọn ẹni tí ń wí pé, “Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”


Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi; Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.


Òdodo rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run, àwọn ìdájọ́ rẹ dàbí ibú ńlá; ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.


Nígbà náà ni Mose na ọwọ́ rẹ̀ sí orí Òkun, ni gbogbo òru náà ni Olúwa fi lé Òkun sẹ́yìn pẹ̀lú ìjì líle láti ìlà-oòrùn wá, ó sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀. Omi Òkun sì pínyà,


Ìwọ fẹ́ èémí rẹ, òkun ru bò wọ́n mọ́lẹ̀. Wọ́n rì bí òjé ni àárín omi ńlá.


Ọlọ́run gbọ́ igbe wọn, Ó sì rántí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Abrahamu, Isaaki àti pẹ̀lú Jakọbu.


Bí afẹ́fẹ́ gúúsù ti í mú òjò wá, bí ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ṣe ń mú ojú ìbínú wá.


ta ni ó sọ fún omi jíjìn pé, ‘Ìwọ gbẹ, èmi yóò sì mú omi odò rẹ gbẹ,’


Ilẹ̀ gbígbẹ lórí omi rẹ̀; yóò sì gbẹ. Nítorí pé ó jẹ́ ilẹ̀ àwọn ère, àwọn ère tí yóò ya òmùgọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù.


Olúwa ti fi ìgbéraga Jakọbu búra pé: “Èmi kì yóò gbàgbé ọ̀kan nínú ohun tí wọ́n ṣe.


Ṣùgbọ́n Ninefe ní jù ọ̀kẹ́ mẹ́fà (12,000) ènìyàn nínú rẹ̀, tí wọn kò mọ ọwọ́ ọ̀tún wọn yàtọ̀ sí ti òsì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọ̀sìn pẹ̀lú. Ṣé èmí kò ha ní kẹ́dùn nípa ìlú ńlá náà?”


Ó bá Òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ; Ó sìsọ gbogbo odò di gbígbẹ. Baṣani àti Karmeli sì rọ, Ìtànná Lebanoni sì rẹ̀ sílẹ̀.


Olúwa mo tí gbọ́ ohùn rẹ; ẹ̀rù sì ba mi fún iṣẹ́ rẹ Olúwa sọ wọn di ọ̀tún ní ọjọ́ ti wa, ní àkókò tiwa, jẹ́ kó di mí mọ̀; ni ìbínú, rántí àánú.


Wọn yóò sì la Òkun wàhálà já, yóò sì bori rírú omi nínú Òkun, gbogbo ibú odò ni yóò sì gbẹ, a ó sì rẹ ìgbéraga Asiria sílẹ̀, ọ̀pá aládé Ejibiti yóò sí lọ kúrò.


Nígbà tí ẹ bá lọ jagun pẹ̀lú àwọn ọ̀tá tó ń ni yín lára ní ilẹ̀ yín, ẹ fun ìpè ìdágìrì pẹ̀lú fèrè. A ó sì rántí yín níwájú Olúwa, Ọlọ́run yín yóò sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín.


Nígbà náà angẹli Olúwa béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ó dé tí o fi na kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ nígbà mẹ́ta yìí? Mo wá síbí láti kọ ojú ìjà sí ọ nítorí ọ̀nà rẹ kò tọ́ níwájú mi.


Ìlú ńlá náà sì pín sí ipa mẹ́ta, àwọn orílẹ̀-èdè sì ṣubú: Babeli ńlá sì wá sí ìrántí níwájú Ọlọ́run, láti fi ago ọtí wáìnì ti ìrunú ìbínú rẹ̀ fún un.


Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga títí dé ọ̀run, Ọlọ́run sì ti rántí àìṣedéédéé rẹ̀.


Wọ́n sì dìde ni kùtùkùtù òwúrọ̀, wọn wólẹ̀ sìn níwájú Olúwa, wọn padà wa sí ilé wọn ni Rama: Elkana si mọ Hana aya rẹ̀: Olúwa sì rántí rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan