Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 7:9 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 akọ àti abo ni wọ́n wọlé pẹ̀lú Noa sínú ọkọ̀ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Noa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 ní meji meji, àtakọ àtabo, gbogbo wọn bá Noa wọ inú ọkọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pa á láṣẹ fún Noa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Nwọn wọle tọ̀ Noa lọ sinu ọkọ̀ ni meji meji, ati akọ ati abo, bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun Noa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 7:9
12 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko inú igbó àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀. Ó sì kó wọn tọ ọkùnrin náà wá láti wo orúkọ tí yóò sọ wọ́n; orúkọ tí ó sì sọ gbogbo ẹ̀dá alààyè náà ni wọ́n ń jẹ́.


Noa sì ṣe ohun gbogbo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un.


Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi sì dé sí ayé.


Méjì méjì ni gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè nínú wọlé pẹ̀lú Noa sínú ọkọ̀.


Gbogbo wọ́n wọlé ní takọ tabo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Noa, Olúwa sì tì wọn mọ́ inú ọkọ̀.


Méjì méjì ni àwọn ẹran tí ó mọ́ àti aláìmọ́, ti ẹyẹ àti ti gbogbo àwọn ẹ̀dá afàyàfà,


Ìkookò àti ọ̀dọ́-àgùntàn yóò jẹun pọ̀, kìnnìún yóò sì jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù, ṣùgbọ́n erùpẹ̀ ni yóò jẹ́ oúnjẹ ejò. Wọn kì yóò pa ni lára tàbí pa ni run ní gbogbo òkè mímọ́ mi,” ni Olúwa wí.


Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run mọ ìgbà tirẹ̀, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèé mọ àkókò ìṣípò padà wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kò mọ ohun tí Ọlọ́run wọn fẹ́.


Kò le sí Júù tàbí Giriki, ẹrú tàbí òmìnira, ọkùnrin tàbí obìnrin nítorí pé ọ̀kan ni nínú Kristi Jesu.


Níbi tí kò gbé sí Giriki tàbí Júù, ìkọlà tàbí aláìkọlà, aláìgbédè, ara Skitia, ẹrú tàbí òmìnira, ṣùgbọ́n Kristi ni ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan