Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 4:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Kaini wí fún Abeli arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a lọ sí oko.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti wà ní oko; Kaini da ojú ìjà kọ Abeli arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Nígbà tí ó yá, Kaini pe Abeli lọ sinu oko. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, Kaini dìde sí Abeli àbúrò rẹ̀, ó sì lù ú pa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Kaini si ba Abeli arakunrin rẹ̀ sọ̀rọ: o si ṣe, nigbati nwọn wà li oko, Kaini dide si Abeli arakunrin rẹ̀, o si lù u pa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 4:8
23 Iomraidhean Croise  

Adamu sì tún bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Seti, tí ó túmọ̀ sí pé, “Ọlọ́run fún mi ní ọmọkùnrin mìíràn ní ipò Abeli tí Kaini pa.”


Ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ sì ti ní ọmọkùnrin méjì, àwọn méjèèjì sì jọ jà lóko, kò sì si ẹni tí yóò là wọ́n, èkínní sì lu èkejì, ó sì pa á.


Abneri sì padà sí Hebroni, Joabu sì bá a tẹ̀ láàrín ojú ọ̀nà láti bá a sọ̀rọ̀ ní àlàáfíà, ó sì gún un níbẹ̀ lábẹ́ inú, ó sì kú, nítorí ẹ̀jẹ̀ Asaheli arákùnrin rẹ̀.


Nígbà tí Jehoramu fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ gidigidi lórí ìjọba baba a rẹ̀, ó sì fi idà pa gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin ọba Israẹli.


Sanballati àti Geṣemu rán iṣẹ́ yìí sí mi pé: “Wá jẹ́ kí a jọ pàdé pọ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn ìletò ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ono.” Ṣùgbọ́n wọ́n ń gbèrò láti ṣe mí ní ibi;


Nígbà náà ni ìwọ ó gbé ojú rẹ sókè láìní àbàwọ́n, àní ìwọ yóò dúró ṣinṣin, ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù,


Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa àwọn ènìyàn búburú nítòótọ́; nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹlẹ́jẹ̀.


Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òhun ẹ̀tàn; wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀;


Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kúnná ju òrí-àmọ́, ṣùgbọ́n ogun wà ni àyà rẹ̀; ọ̀rọ̀ rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ, ṣùgbọ́n idà fífàyọ ní wọn.


Àfi èpè, irọ́ pípa àti ìpànìyàn olè jíjà àti panṣágà. Wọ́n rú gbogbo òfin, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sì ń gorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀.


Nítorí tí ọmọkùnrin kò bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọbìnrin sì dìde sí ìyá rẹ̀, aya ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀, ọ̀tá olúkúlùkù ni àwọn ará ilé rẹ̀.


Tí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń yan odì pẹ̀lú ìríra tí ẹlòmíràn tàbí ju nǹkan sí i pẹ̀lú èrò, tí ó sì kú.


Kí ẹ̀yin lè jẹ̀bi gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo tí ẹ ta sílẹ̀ ní ayé, láti ẹ̀jẹ̀ Abeli títí dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah ọmọ Berekiah ẹni tí ẹ pa nínú tẹmpili láàrín ibi pẹpẹ àti ibi ti ẹ yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run.


láti ẹ̀jẹ̀ Abeli wá, títí ó sì fi dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah, tí ó ṣègbé láàrín pẹpẹ àti tẹmpili: lóòótọ́ ni mo wí fún yín ìran yìí ni yóò ru gbogbo ẹ̀bi àwọn nǹkan wọ̀nyí.


Jesu sì wí fún un pé, “Judasi, ìwọ yóò ha fi ìfẹnukonu fi Ọmọ ènìyàn hàn?”


Nípa ìgbàgbọ́ ní Abeli rú ẹbọ sí Ọlọ́run tí ó sàn ju ti Kaini lọ, nípa èyí tí a jẹ́rìí rẹ̀ pe olódodo ni, Ọlọ́run sí ń jẹ́rìí ẹ̀bùn rẹ̀: Àti nípa rẹ̀ náà, bí o ti jẹ́ pé o ti kú, síbẹ̀ o ń fọhùn.


Àti sọ́dọ̀ Jesu alárinà májẹ̀mú tuntun, àti si ibi ẹ̀jẹ̀ ìbùwọ́n ni, ti ń sọ̀rọ̀ ohun tí ó dára ju ti Abeli lọ.


Ègbé ni fún wọn! Nítorí tí wọ́n ti rìn ní ọ̀nà Kaini, wọ́n sì fi ìwọra súré sínú ìṣìnà Balaamu nítorí ère, wọn ṣègbé nínú ìṣọ̀tẹ̀ Kora.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan