Gẹnẹsisi 4:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní7 Bí ìwọ bá ṣe ohun tí ó tọ́, ṣé ìwọ kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ṣe ohun tí ó tọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ ní ọ ní ìní, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ ṣe àkóso rẹ̀.” Faic an caibideilYoruba Bible7 Bó bá jẹ́ pé o ṣe rere ni, ara rẹ ìbá yá gágá, ẹbọ rẹ yóo sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Ṣugbọn nítorí pé ibi ni o ṣe, ẹ̀ṣẹ̀ ba dè ọ́ lẹ́nu ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ jọba lé ọ lórí ṣugbọn tìrẹ ni láti ṣẹgun rẹ̀.” Faic an caibideilBibeli Mimọ7 Bi iwọ ba ṣe rere, ara ki yio ha yá ọ? bi iwọ kò ba si ṣe rere, ẹ̀ṣẹ ba li ẹnu-ọ̀na, lọdọ rẹ ni ifẹ rẹ̀ yio ma fà si, iwọ o si ma ṣe alakoso rẹ̀. Faic an caibideil |
Nítorí náà, ẹ mú akọ ẹgbọrọ màlúù méje, àti àgbò méje, kí ẹ sì tọ̀ Jobu ìránṣẹ́ mi lọ, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sísun fún ara yín; Jobu ìránṣẹ́ mi yóò sì gbàdúrà fún yin; nítorí pé àdúrà rẹ̀ ní èmi yóò gbà; kí èmi kí ó má ba ṣe si yín bí ìṣìnà yín, ní ti pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi bi Jobu ìránṣẹ́ mi ti ṣe.