Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 4:12 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Bí ìwọ bá ro ilẹ̀, ilẹ̀ kì yóò fi agbára rẹ̀ so èso rẹ̀ fún ọ mọ́. Ìwọ yóò sì jẹ́ ìsáǹsá àti alárìnkiri ni orí ilẹ̀ ayé.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Láti òní lọ, nígbà tí o bá dá oko, ilẹ̀ kò ní fi gbogbo agbára rẹ̀ so èso fún ọ mọ́, ìsáǹsá ati alárìnká ni o óo sì jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Nigbati iwọ ba ro ilẹ, lati isisiyi lọ, ki yio fi agbara rẹ̀ so eso fun ọ mọ; isansa ati alarinkiri ni iwọ o ma jẹ li aiye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 4:12
16 Iomraidhean Croise  

Kaini wí fún Olúwa pé, “Ẹrù ìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi pọ̀ ju èyí tí mo le rù lọ.


Lónìí, ìwọ lé mi kúrò lórí ilẹ̀, mó sì di ẹni tí ó fi ara pamọ́ kúrò ní ojú rẹ, èmi yóò sì di ìsáǹsá àti alárìnkiri ní ayé, ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi, yóò sì pa mí.”


Ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀ nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú rẹ̀;


Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe kiri kí wọn máa tọrọ oúnjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn


Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn yóò máa joró rẹ̀ títí ikú má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ràn án lọ́wọ́.


Ọlọ́run mi yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí pé wọn kò gbọ́rọ̀ sí i; wọn yóò sì di alárìnkiri láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.


Oko di ìgboro, ilẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a fi ọkà ṣòfò: ọtí wáìnì tuntun gbẹ, òróró ń bùṣe.


Èmi yóò dojúkọ yín títí tí ẹ̀yin ó fi di ẹni ìkọlù; àwọn tí ó kórìíra yín ni yóò sì ṣe àkóso lórí yín. Ìbẹ̀rù yóò mú yín dé bi pé ẹ̀yin yóò máa sá káàkiri nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé yín.


Ẹ ó máa lo agbára yín lásán torí pé ilẹ̀ yín kì yóò so èso, bẹ́ẹ̀ ni àwọn igi yín kì yóò so èso pẹ̀lú.


“ ‘Èmi yóò jẹ́ kí ó burú fún àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ ìgbèkùn dé bi pé ìró ewé tí ń mì lásán yóò máa lé wọn sá. Ẹ ó máa sá bí ẹni tí ń sá fún idà. Ẹ ó sì ṣubú láìsí ọ̀tá láyìíká yín


Nítorí a tẹrí ẹ̀dá ba fún asán, kì í ṣe bí òun ti fẹ́, ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ẹni tí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní ìrètí.


Ṣùgbọ́n bí o kò bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì rọra máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí, gbogbo ègún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan