Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 4:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Adamu sì bá aya rẹ̀ Efa lòpọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Kaini. Ó wí pé, “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa ni mo bí ọmọ ọkùnrin.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Nígbà tí ó yá, Adamu bá Efa, aya rẹ̀, lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó ní, “Pẹlu ìrànlọ́wọ́ OLUWA, mo ní ọmọkunrin kan,” ó sọ ọmọ náà ní Kaini.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 ADAMU si mọ̀ Efa aya rẹ̀; o si loyun, o si bí Kaini, o si wipe, Mo ri ọkunrin kan gbà lọwọ OLUWA.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 4:1
8 Iomraidhean Croise  

Èmi yóò sì fi ọ̀tá sí àárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà; òun yóò fọ́ orí rẹ, ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”


Lẹ́yìn tí ó ti lé ènìyàn jáde tán, ó fi àwọn Kérúbù àti idà iná tí ó ń kọ mọ̀nàmọ́ná síwájú àti sẹ́yìn láti ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè, ní ìhà ìlà-oòrùn ọgbà Edeni.


Lẹ́yìn náà, ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn tí a pè ní Abeli. Abeli jẹ́ darandaran, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀.


Adamu sì tún bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Seti, tí ó túmọ̀ sí pé, “Ọlọ́run fún mi ní ọmọkùnrin mìíràn ní ipò Abeli tí Kaini pa.”


Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Noa, ó sì wí pé, “Eléyìí ni yóò tù wá nínú ni iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi gégùn ún.”


Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa: ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.


Nísinsin yìí, pa gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó ti súnmọ́ ọkùnrin,


Kì í ṣe bí Kaini, tí í ṣe ẹni búburú, tí o sì pa arákùnrin rẹ̀. Nítorí kín ni ó sì ṣe pa á? Nítorí tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́ búburú ṣùgbọ́n tí arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ òdodo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan