Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 30:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Báyìí ni Rakeli fi Biliha fún Jakọbu ní aya, ó sì bá a lòpọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Ó bá fún Jakọbu ní Biliha, iranṣẹbinrin rẹ̀ kí ó fi ṣe aya, Jakọbu sì bá a lòpọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 O si fi Bilha, iranṣẹbinrin rẹ̀, fun u li aya: Jakobu si wọle tọ̀ ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 30:4
12 Iomraidhean Croise  

Nítorí náà, Sarai wí fún Abramu pé, “Kíyèsi i Olúwa ti sé mi ní inú, èmi kò sì bímọ, wọlé tọ ọmọ ọ̀dọ̀ mi lọ, bóyá èmi yóò le ti ipasẹ̀ rẹ̀ ní ọmọ.” Abramu sì gba ohun tí Sarai sọ.


ó sì wí fún Abrahamu pé, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrú yìí kò ní bá ọmọ mi Isaaki pín ogún.”


Àlè rẹ̀ tí ń jẹ́ Reuma náà bí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí fun un: Teba, Gahamu, Tahasi àti Maaka.


Abrahamu sì tún fẹ́ aya mìíràn, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ketura.


Ṣùgbọ́n kí Abrahamu tó kú, Abrahamu fún àwọn ọmọ tí àwọn àlè rẹ̀ bí fún un ní ẹ̀bùn, ó sì lé wọn jáde lọ fún Isaaki ọmọ rẹ sí ilẹ̀ ìlà-oòrùn.


Labani sì fi Biliha ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Rakeli bí ìránṣẹ́.


Biliha sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Jakọbu.


Ó sì ti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn síwájú, Lea àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọ̀wọ́ kejì tí ó tẹ̀lé wọn, Rakeli àti Josẹfu sì wà lẹ́yìn pátápátá.


Nígbà tí Israẹli sì ń gbé ní ibẹ̀, Reubeni wọlé tọ Biliha, àlè (ìyàwó tí a kò fi owó fẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀) baba rẹ̀ lọ, ó sì bá a lòpọ̀, Israẹli sì gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Jakọbu sì bí ọmọkùnrin méjìlá:


Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Biliha ẹni tí Labani fi fún Rakeli ọmọ rẹ̀ bí fún Jakọbu. Wọ́n jẹ́ méje lápapọ̀.


“Báyìí ni Olúwa wí, Kíyèsi i, ‘Èmi ó jẹ́ kí ibi kí ó dìde sí ọ láti inú ilé rẹ wá, èmi ó sì gba àwọn obìnrin rẹ lójú rẹ, èmi ó sì fi wọ́n fún aládùúgbò rẹ, òun ó sì bá àwọn obìnrin rẹ sùn níwájú òòrùn yìí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan