Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 3:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Nígbà náà ni ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ gbọ́ ìró Olúwa Ọlọ́run bí ó ti ń rìn nínú ọgbà, nígbà tí ojú ọjọ́ tura, wọ́n sì fi ara pamọ́ kúrò níwájú Olúwa Ọlọ́run sí àárín àwọn igi inú ọgbà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbúròó OLUWA Ọlọrun tí ń rìn ninu ọgbà. Wọ́n bá sá pamọ́ sí ààrin àwọn igi ọgbà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Nwọn si gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun, o nrìn ninu ọgbà ni itura ọjọ́: Adamu ati aya rẹ̀ si fi ara wọn pamọ́ kuro niwaju OLUWA Ọlọrun lãrin igi ọgbà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 3:8
20 Iomraidhean Croise  

Olúwa sì bá tirẹ̀ lọ, nígbà tí ó bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, Abrahamu sì padà sílé.


Ó dáhùn pé, “Mo gbúròó rẹ̀ nínú ọgbà, ẹ̀rù sì bà mí, nítorí pé, mo wà ní ìhòhò, mo sì fi ara pamọ́.”


Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ tí ó nípọn jẹ ìbora fún un, tí kò fi lè ríran; ó sì ń rìn nínú àyíká ọ̀run.


Bí mo bá bò ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́lẹ̀ bí Adamu ni pápá, ẹ̀bi mi pamọ́ ni àyà mi.


Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé:


Ojú Olúwa wà níbi gbogbo, Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.


Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè sápamọ́ sí ibi kọ́lọ́fín kan, kí èmi má ba a rí?” ni Olúwa wí. “Ǹjẹ́ èmi kò ha a kún ọ̀run àti ayé bí?” ni Olúwa wí.


Àwọn ibi gíga tí ẹ tí ń hùwà búburú ni a o parun— èyí ni ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli. Ẹ̀gún ọ̀gàn àti ẹ̀gún òṣùṣú yóò hù jáde, yóò sì bo àwọn pẹpẹ wọn. Wọn yóò sọ fún àwọn òkè gíga pé, “Bò wá mọ́lẹ̀!” àti fún àwọn òkè kéékèèkéé pé, “Ṣubú lù wá!”


Èmi yóò wà pẹ̀lú yín: Èmi yóò máa jẹ́ Ọlọ́run yín: Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ènìyàn mi.


Ṣùgbọ́n Jona dìde kúrò láti sálọ sí Tarṣiṣi kúrò níwájú Olúwa, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Joppa, ìbí ti ó tí rí ọkọ̀ kan tí ń lọ sí Tarṣiṣi: lẹ́yìn ti ó sanwó ọkọ̀, ó wọlé sínú rẹ̀, láti bá wọn lọ sí Tarṣiṣi kúrò níwájú Olúwa.


Àwọn ẹni tí ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lọ́kàn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn pẹ̀lú sì tún ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, àti pé, èrò ọkàn wọn tí ó jẹ́ ọ̀nà ìfinisùn, sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn ní ìsinsin yìí.


Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń rìn láàrín àgọ́ láti dáàbò bò ọ́ àti láti fi àwọn ọ̀tá à rẹ lé ọ lọ́wọ́. Àgọ́ rẹ ní láti jẹ́ mímọ́, nítorí kí ó má ba à rí ohun àìtọ́ láàrín yín kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ yín.


Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn mìíràn tí ì gbọ́ ohùn Ọlọ́run rí, tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti inú iná, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti gbọ́ tí ẹ sì yè?


Ṣùgbọ́n èéṣe tí àwa yóò fi kú? Iná ńlá yìí yóò jó wa run, bí àwa bá sì tún gbọ́ ohun Olúwa Ọlọ́run wa, àwa ó kú.


Kò sí ẹ̀dá kan tí kò farahàn níwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo ni ó wà níhòhò tí a sì ṣípáyà fún ojú rẹ̀, níwájú ẹni tí àwa yóò jíyìn.


Àwọn ọba ayé àti àwọn ọlọ́lá àti àwọn olórí ogun, àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára, àti olúkúlùkù ẹrú, àti olúkúlùkù òmìnira, sì fi ara wọn pamọ́ nínú ihò ilẹ̀, àti nínú àpáta orí òkè;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan