Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 3:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Nígbà náà ni ojú àwọn méjèèjì sì là, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn wà ní ìhòhò; wọ́n sì rán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sì fi bo ara wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Ojú àwọn mejeeji bá là, wọ́n sì mọ̀ pé ìhòòhò ni àwọn wà, wọ́n bá gán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sán an mọ́ ìdí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Oju awọn mejeji si là, nwọn si mọ̀ pe nwọn wà ni ìhoho; nwọn si gán ewe ọpọtọ pọ̀, nwọn si dá ibantẹ fun ara wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 3:7
13 Iomraidhean Croise  

Ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ sì wà ní ìhòhò, ojú kò sì tì wọ́n.


“Nítorí Ọlọ́run mọ̀ wí pé, bí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀, ojú yín yóò là, ẹ̀yin yóò sì dàbí Ọlọ́run, ẹ̀yin yóò sì mọ rere yàtọ̀ sí búburú.”


Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n wọ ìlú náà, Eliṣa wí pé, “Olúwa, la ojú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kí wọn kí ó lè ríran.” Nígbà náà Olúwa la ojú wọn, wọ́n sì ríran, wọ́n sì wà níbẹ̀, nínú Samaria.


Ibùsùn kúrú púpọ̀ fún ìnara lé lórí, ìbora kò fẹ̀ tó láti yí ara yín ká.


Ìhòhò rẹ ni a ó sí síta àti ìtìjú rẹ ni a ó ṣí sílẹ̀. Èmi yóò sì gba ẹ̀san; Èmi kì yóò sì dá ẹnìkan sí.”


Òwú wọn kò wúlò fún aṣọ rírán; wọn kò lè fi aṣọ tí wọ́n hun bo ara wọn. Iṣẹ́ wọn jẹ́ ti ibi, ìwà jàǹdùkú sì kún ọwọ́ wọn.


Jerusalẹmu sì ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ ó sì ti di aláìmọ́. Àwọn tí ó ń tẹríba fún un sì kẹ́gàn rẹ̀, nítorí wọ́n ti rí ìhòhò rẹ̀; ó kérora fúnrarẹ̀, ó sì lọ kúrò.


Ní ipò òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìjìyà oró, ó sì rí Abrahamu ní òkèrè, àti Lasaru ní oókan àyà rẹ̀.


Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà ara tí a rò pé kò lọ́lá rárá ni àwa ń fi ọlá fún jùlọ. Àwọn ẹ̀yà ara tí a rò pé ko yẹ rárá ni àwa ń fi si ipò ọlá ẹ̀yẹ tí ó ga jùlọ.


Ìran tí ojú rẹ yóò rí, yóò sọ ọ́ di òmùgọ̀.


(Ó ṣe èyí láti fi kọ́ àwọn ìran Israẹli tí kò rí ogun rí níbí a ti ṣe ń jagun):


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan