Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 3:6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Nígbà tí obìnrin náà rí i wí pé èso igi náà dára fún oúnjẹ àti pé, ó sì dùn ún wò, àti pé ó ń mú ni ní ọgbọ́n, ó mú díẹ̀ níbẹ̀, ó sì jẹ ẹ́. Ó sì mú díẹ̀ fún ọkọ rẹ̀, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Nígbà tí obinrin yìí ṣe akiyesi pé èso igi náà dára fún jíjẹ ati pé ó dùn ún wò, ó sì wòye bí yóo ti dára tó láti jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ó mú ninu èso igi náà, ó jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀, ọkọ rẹ̀ náà sì jẹ ẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Nigbati obinrin na si ri pe, igi na dara ni jijẹ, ati pe, o si dara fun oju, ati igi ti a ifẹ lati mu ni gbọ́n, o mu ninu eso rẹ̀ o si jẹ, o si fi fun ọkọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, on si jẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 3:6
19 Iomraidhean Croise  

Ọkùnrin náà wí pé, “Obìnrin tí ìwọ fi fún mi, ni ó fún mi nínú èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.”


Ọlọ́run sì wí fún Adamu pé, “Nítorí pé ìwọ fetí sí aya rẹ, ìwọ sì jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀,’ “Ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ; nínú ọ̀pọ̀ làálàá ni ìwọ yóò jẹ nínú rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.


lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Josẹfu, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lòpọ̀!”


Àwọn ọmọ Ọlọ́run rí i wí pé àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lẹ́wà, wọ́n sì fẹ́ èyíkéyìí tí ó wù wọ́n ṣe aya.


Ó sì ṣe, ní ìgbà àṣálẹ́ kan, Dafidi sì dìde ní ibùsùn rẹ̀, ó sì ń rìn lórí òrùlé ilé ọba, láti orí òrùlé náà ni ó sì rí obìnrin kan tí ó ń wẹ̀ ara rẹ̀; obìnrin náà sì ṣe arẹwà lójú láti wò.


Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn Ọlọ́run náà sì padà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì jẹ oúnjẹ ó sì mu omi ní ilé rẹ̀.


“Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mú, èmi yó ha ṣe tẹjúmọ́ wúńdíá?


“Ọmọ ènìyàn, kíyèsi i, mo mú ìfẹ́ ojú rẹ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, nípa lílù kan. Ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ gbààwẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sọkún, bẹ́ẹ̀ ni omijé ojú rẹ kò gbọdọ̀ kán sílẹ̀.


Sọ fún ilé Israẹli, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, èmi yóò sọ ibi mímọ́ mi di ibi àìmọ́ tayọ agbára yín, ìfẹ́ ojú yín, ìkáàánú yín, àti ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin tí ẹ̀yin fi sílẹ̀ sẹ́yìn yóò ṣubú nípa idà.


“Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ, Ọmọ ènìyàn, kì yóò ha jẹ́ pé, ní ọjọ́ náà, nígbà ti mo bá gba agbára wọn, ayọ̀ wọn àti ògo wọn, ìfẹ́ ojú wọn, ohun tí wọn gbé ọkàn wọn lé, àti àwọn ọmọ ọkùnrin wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ obìnrin wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn,


Bí i Adamu, wọ́n da májẹ̀mú wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi níbẹ̀.


Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìnrin kan ní ìwòkuwò, ti bà ṣe panṣágà nínú ọkàn rẹ̀.


Adamu kọ́ ni a tànjẹ, ṣùgbọ́n obìnrin náà ni a tàn tí ó sì di ẹlẹ́ṣẹ̀.


Nígbà tí mo rí ẹ̀wù Babeli kan tí ó dára nínú ìkógun, àti igba ṣékélì fàdákà àti odindi wúrà olóṣùnwọ́n àádọ́ta ṣékélì, mo ṣe ojúkòkòrò wọn mo sì mú wọn. Mo fi wọ́n pamọ́ ní abẹ́ àgọ́ mi àti fàdákà ní abẹ́ rẹ̀.”


Nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé: ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ojú, àti ìgbéraga ti ohun ti ó ní àti ohun tí ó ṣe: kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bí kò ṣe láti ọwọ́ ayé.


Fún gbogbo ọjọ́ méje tí wọ́n fi ṣe àsè náà ni ó fi sọkún, nítorí náà ní ọjọ́ keje ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ fún un nítorí pé ó yọ ọ́ lẹ́nu ní ojoojúmọ́. Òun náà sì sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ènìyàn rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan