Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 3:5 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 “Nítorí Ọlọ́run mọ̀ wí pé, bí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀, ojú yín yóò là, ẹ̀yin yóò sì dàbí Ọlọ́run, ẹ̀yin yóò sì mọ rere yàtọ̀ sí búburú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Ọlọrun sọ bẹ́ẹ̀ nítorí ó mọ̀ pé bí ẹ bá jẹ ẹ́, ojú yín yóo là, ẹ óo sì dàbí òun alára, ẹ óo mọ ire yàtọ̀ sí ibi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Nitori Ọlọrun mọ̀ pe, li ọjọ́ ti ẹnyin ba jẹ ninu rẹ̀, nigbana li oju nyin yio là, ẹnyin o si dabi Ọlọrun, ẹ o mọ̀ rere ati buburu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 3:5
31 Iomraidhean Croise  

ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti èso igi ìmọ̀ búburú, nítorí ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ ẹ́ ni ìwọ yóò kùú.”


Olúwa Ọlọ́run sì mú kí onírúurú igi hù jáde láti inú ilẹ̀: àwọn igi tí ó dùn ún wò lójú, tí ó sì dára fún oúnjẹ. Ní àárín ọgbà náà ni igi ìyè àti igi tí ń mú ènìyàn mọ rere àti búburú wà.


Ó dáhùn pé, “Mo gbúròó rẹ̀ nínú ọgbà, ẹ̀rù sì bà mí, nítorí pé, mo wà ní ìhòhò, mo sì fi ara pamọ́.”


Olúwa Ọlọ́run sì wí pé, “Ọkùnrin náà ti dàbí ọ̀kan lára wa, ó mọ rere àti búburú. A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó na ọwọ́ rẹ̀ kí ó mú lára èso igi ìyè kí ó sì jẹ, kí ó sì wà láààyè títí láéláé.”


Nígbà náà ni ojú àwọn méjèèjì sì là, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn wà ní ìhòhò; wọ́n sì rán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sì fi bo ara wọn.


Nígbà náà ni ọba Israẹli kó àwọn wòlíì jọ, bí irínwó (400) ọkùnrin. Ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé kí n lọ sí Ramoti Gileadi lọ jagun, tàbí kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ̀?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Lọ, nítorí tí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”


Nísinsin yìí, ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah ó tàn yín àti ṣì yín tọ́ ṣọ́nà báyìí. Ẹ má ṣe gbà á gbọ́, nítorí tí kò sí ọlọ́run orílẹ̀-èdè mìíràn tàbí ìjọba tí ó ní agbára láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi tàbí lọ́wọ́ àwọn baba mi, mélòó mélòó wa ni Ọlọ́run yín tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi!”


tí ó wí pé, “Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa; àwa ní ètè wa: Ta ni ọ̀gá wa?”


Ẹ má ṣe ṣi orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín lò, torí pé ẹnikẹ́ni tí o bá ṣi orúkọ rẹ̀ lò kì yóò lọ láìjẹ̀bi.


Farao dáhùn wí pé, “Ta ni Olúwa, tí èmi yóò fi gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, tí èmi yóò fi jẹ́ kí Israẹli ó lọ? Èmi kò mọ Olúwa, èmi kò sì ní jẹ́ kí Israẹli ó lọ.”


Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọsánmọ̀; Èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá-ògo.”


Nítorí pé ẹ̀yin ti ba ọkàn àwọn olódodo jẹ́ pẹ̀lú irọ́ yín, nígbà tí Èmi kò mú ìbànújẹ́ bá wọn, àti nítorí ẹ̀yin ti mú ọkàn àwọn ènìyàn búburú le, kí wọ́n má ba à kúrò nínú ọ̀nà ibi wọn dé bi tí wọn yóò fi gba ẹ̀mí wọn là,


“Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tire kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ ìjẹ́pípé náà, o kún fún ọgbọ́n, o sì pé ní ẹwà.


“Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tire pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè sí mi, ìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run; Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà, ní àárín gbùngbùn Òkun.” Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.


Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,” ní ojú àwọn tí ó pa ọ́? Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run, ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́.


Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Èmi lòdì sí ọ, Farao ọba Ejibiti ìwọ ẹ̀mí búburú ńlá inú Òkun tí ó dùbúlẹ̀ sí àárín àwọn odò ṣíṣàn rẹ èyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili; èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.”


Ó sọ pé, “Èyí ha kọ́ ni Babeli ńlá tí mo kọ́ gẹ́gẹ́ bí ilé ọba, nípa agbára à mi àti fún ògo ọláńlá à mi?”


Àwọn alákòóso ọba, ìjòyè, baálẹ̀, olùdámọ̀ràn, àti àwọn olórí gbìmọ̀ pọ̀ wí pé kí ọba kéde òfin kan pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àdúrà sí Ọlọ́run tàbí ènìyàn kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, yàtọ̀ fún ìwọ ọba, a ó ju ẹni náà sí inú ihò kìnnìún.


Ṣùgbọ́n bí ojú rẹ kò bá dára, gbogbo ara rẹ ni yóò kún fún òkùnkùn. Bí ìmọ́lẹ̀ ti ó wà nínú rẹ bá wá jẹ́ òkùnkùn, òkùnkùn náà yóò ti pọ̀ tó!


láti là wọ́n lójú, kí wọn lè yípadà kúrò nínú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ agbára Satani sí Ọlọ́run, kí wọn lè gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àti ogún pẹ̀lú àwọn tí a sọ di mímọ́ nípa ìgbàgbọ́ nínú mi.’


Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí, kí ó má bà á jẹ́ pé, bí ejò ti tan Efa jẹ́ nípasẹ̀ àrékérekè rẹ̀, a lè mú ọkàn yín ṣáko lọ kúrò nínú òtítọ́ yín àti ìfarajì fún Kristi.


Nínú àwọn ẹni tí ọlọ́run ayé yìí ti sọ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ dí afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere Kristi tí ó lógo, ẹni tí í ṣe àwòrán Ọlọ́run, má ṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn.


Òun yóò lòdì sí, yóò sì gbé ara rẹ̀ ga sí gbogbo ohun tí a ń pè ní Ọlọ́run tàbí tí a ń sìn, dé ibi pé yóò gbé ara rẹ̀ jókòó nínú tẹmpili Ọlọ́run, tí yóò sì pe ara rẹ̀ ní Ọlọ́run.


Ó sì ń tán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ nípa àwọn ohun ìyanu tí a fi fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà; ó wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti ya àwòrán fún ẹranko náà tí o tí gbá ọgbẹ́ idà, tí ó sì yè.


Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún dragoni náà, nítorí tí o fún ẹranko náà ní àṣẹ, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, wí pé, “Ta ni o dàbí ẹranko yìí? Ta ni ó sì lè bá a jagun?”


(Ó ṣe èyí láti fi kọ́ àwọn ìran Israẹli tí kò rí ogun rí níbí a ti ṣe ń jagun):


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan