Gẹnẹsisi 26:9 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní9 Nígbà náà ni Abimeleki ránṣẹ́ pe Isaaki ó sì wí fun pé, “Nítòótọ́, aya rẹ ni obìnrin yìí í ṣe, èéṣe tí ìwọ fi wí fún wa pé arábìnrin mi ni?” Isaaki sì fèsì pé, “Nítorí mo rò pé mo le pàdánù ẹ̀mí mi nítorí rẹ̀.” Faic an caibideilYoruba Bible9 Abimeleki bá pe Isaaki, ó wí pé, “Àṣé iyawo rẹ ni Rebeka! Kí ni ìdí tí o fi pè é ní arabinrin rẹ fún wa?” Isaaki bá dáhùn pé, “Mo rò pé wọ́n lè pa mí nítorí rẹ̀ ni.” Faic an caibideilBibeli Mimọ9 Abimeleki si pè Isaaki, o si wipe, Kiyesi i, nitõtọ aya rẹ ni iṣe: iwọ ha ti ṣe wipe, Arabinrin mi ni? Isaaki si wi fun u pe, Nitoriti mo wipe, ki emi ki o má ba kú nitori rẹ̀. Faic an caibideil |