Gẹnẹsisi 26:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní7 Nígbà tí àwọn ọkùnrin ìlú náà bi í léèrè ní ti aya rẹ̀, ó sì wí pé, “Arábìnrin mi ní í ṣe,” nítorí tí ó bẹ̀rù láti jẹ́wọ́ wí pé, “Aya mi ni.” Ó ń rò wí pé, “Kí àwọn ọkùnrin ibẹ̀ náà má ba à pa mí nítorí Rebeka, nítorí tí òun ní ẹwà púpọ̀.” Faic an caibideilYoruba Bible7 Nígbà tí àwọn ará ìlú náà bèèrè bí Rebeka ti jẹ́ sí i, ó sọ fún wọn pé arabinrin òun ni. Ẹ̀rù bà á láti jẹ́wọ́ fún wọn pé iyawo òun ni, nítorí ó rò pé àwọn ará ìlú náà lè pa òun nítorí pe Rebeka jẹ́ arẹwà obinrin. Faic an caibideilBibeli Mimọ7 Awọn ọkunrin ibẹ̀ na bi i lẽre niti aya rẹ̀: o si wipe, Arabinrin mi ni: nitoriti o bẹ̀ru ati wipe, Aya mi ni; o ni, ki awọn ọkunrin ibẹ̀ na ki o má ba pa mi nitori Rebeka; nitoriti on li ẹwà lati wò. Faic an caibideil |