Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 26:11 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Nígbà náà ni Abimeleki pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin yìí tàbí aya rẹ̀ yóò jẹ̀bi ikú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Nítorí náà Abimeleki kìlọ̀ fún gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan ọkunrin yìí tabi aya rẹ̀, pípa ni wọn yóo pa á.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Abimeleki si kìlọ fun gbogbo awọn enia rẹ̀ wipe, Ẹnikẹni ti o ba tọ́ ọkunrin yi tabi aya rẹ̀, kikú ni yio kú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 26:11
5 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un nínú àlá náà pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé pẹ̀lú òtítọ́ inú ni ìwọ ṣe èyí, èyí ni mo fi pa ọ́ mọ́ tí ń kò jẹ́ kí o ṣẹ̀ sí mi. Ìdí nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin náà.


Ní ọdún náà, Isaaki gbin ohun ọ̀gbìn sí ilẹ̀ náà, ó sì kórè rẹ̀ ní ìlọ́po ọgọ́ọ̀rún ni ọdún kan náà, nítorí Ọlọ́run bùkún un.


“Má ṣe fọwọ́ kan ẹni ààmì òróró mi, má sì ṣe wòlíì mi níbi.”


Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sùn pẹ̀lú aya aláya; kò sí ẹni tí ó fọwọ́ kàn án tí yóò lọ láìjìyà.


Nítorí báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Lẹ́yìn ògo rẹ̀ ni a ti rán mi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ń kó yin: nítorí ẹni tí ó tọ́ yin, ó tọ́ ọmọ ojú rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan